Wọ́n ti yọ Igbákejì Gómìnà Edo, Philip Shuaib, nípò

Wọ́n ti yọ Igbákejì Gómìnà Edo, Philip Shuaib, nípò

Ọrẹ Òtítọ́jù
A fi bí àlá ojú oorun lọ̀rọ̀ dà bí Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Edo ti fòùntẹ̀ jan àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ tó gbọ́ àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Ọgbẹni Philip Shuaibu, bí wọn ti yọ ọkùnrin ọhún kúò nípò fódá.

Awọn aṣofin naa dori ipinnu yii lasiko ijokoo wọn laaarọ ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

Ṣaaju ni wọn ti kọwe awọn ẹsun kan ta ko Shuaibu, ti kọmiṣanna feto idajọ ipinlẹ naa si yan igbimọ ẹlẹni meje kan, eyi ti Adajọ-fẹyinti S. A. Omonua, jẹ alaga rẹ.

Lara awọn ẹsun ti wọn ka si ọkunrin naa lẹsẹ ni pe o tu awọn aṣiri ijọba kan ti ko yẹ ko tu sita, wọn si tun lo ṣe awọn owo kan baṣubaṣu lọfiisi rẹ.

Amọ gẹgẹ bi Omonua ṣe sọ lasiko to n jabọ iwadii ati aba wọn fawọn aṣofin naa lọjọ Ẹti, ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin yii, o ni awọn kọwe si igbakeji gomina ọhun lati waa sọ awijare rẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an, ṣugbọn Philip Shuaibu ko yọju, ko si ran aṣoju kankan wa.

Adajọ naa ni: “Koda, titi di oni yii, a tun mọ-ọn-mọ sun ijokoo wa siwaju lati fun Shuaibu lanfaani ‘waa-wi-tẹnu-ẹ’ sibẹ, niṣe lo dagunla patapata.

Ṣaaju asiko yii ni agbẹjọro fun igbakeji gomina ọhun, Amofin agba Ọjọgbọn Ọladoyin Awoyale, ti kọwe pe onibaara oun ko ni i le ba wọn kopa kankan ninu ijokoo igbẹjọ naa latari aṣẹ ile-ẹjọ giga apapọ ilu Abuja kan to kede pe ki gbogbo awọn tọrọ naa kan ṣi ṣe afaro lori ẹsun ọhun na. Wọn ni ki ijokoo iyọnipo kankan ma ti i waye, Awoyale si rọ igbimọ naa lati bọwọ fun aṣẹ ile-ẹjọ giga yii titi di ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin yii, ti igbẹjọ yoo tẹsiwaju ni kootu, amọ wọn ko ṣe bẹẹ.

Ọjọ Mọnde ọhun lawọn aṣofin fountẹ jan abọ iwadii, ti wọn si buwọ lu iyọnipo Shuaibu.

Tẹ o ba gbagbe, lati ọpọ oṣu sẹyin ni lọgbọlọgbọ ti n lọ labẹnu laarin Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki, ati igbakeji rẹ latari awọn aigbọra-ẹni-ye kan.

Ina ija naa tubọ gbilẹ nigba ti igbakeji gomina kede pe oun yoo dije-dupo gomina ninu eto idibo to n bọ loṣu Kọkanla, ọdun yii, amọ ọga rẹ kọ lati ṣatilẹyin fun un.

Látìgbà náà ni ẹ̀kọ ò ti ṣojú mímu láàrin wọn, bí èkúté àti ológbò ni ìṣesí wọn látìgbà yìí wá.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here