Kìnìún fa òṣìṣẹ́ Fásitì OAU ya lẹ́yìn ọdún mẹ́sàn-án tó ti ń fún-un ní oúnjẹ

Kìnìún fa òṣìṣẹ́ Fásitì OAU ya lẹ́yìn ọdún mẹ́sàn-án tó ti ń fún-un ní oúnjẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àrọwà wo ni ká pa báyìí fún ẹni tí kìnìún pa mọ̀lẹ́bí rẹ̀ jẹ ní bí
òṣìṣẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì
Obafemi Awolowo nílùú Ilé Ife, Olabode Olawuyi, ṣe pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ṣọ́wọ́ kìnìnú tó ti ń sìn fun ọdún mẹ́sàn án.

Àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ilé ẹ̀kọ́ Fásitì náà, Abiodun Olarewaju fi lédè fún àwọn akọ̀ròyìn, Olawuyi ló jẹ́ onímọ̀ nípa ẹranko, tó sì ti ń bá ilé ẹ̀kọ́ náà ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ẹ̀ka ilé ẹ̀kọ́ tó ń mójútó àwọn ẹranko nínú igbó, ‘Zoo’.

Olarewaju ní kìnìnú, tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́sàn án, kọlu Olawuyi lásìkò tó ń fún un ní oúnjẹ ní gbàgede ẹranko tó wà nínú ilé ẹ̀kọ́ Fásitì Obafemi Awolowo.

Gẹ́gẹ́ bí Olarewaju ṣe ṣàlàyé, gbogbo òṣìṣẹ́ yòókù tó wà ní ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé sa gbogbo akitiyan àti agbára wọn láti dóòlà ẹ̀mí Olawuyi ṣùgbọ́n ẹranko kininu náà ti gba ẹ̀mí lẹ́nu ọ̀gá wọn.
“ Kété tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ ni a fi tó Ọ̀gá àgbà Fásitì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Adebayo Simeon létí, tó sì ní láti kúrò níbi ìpàdé tó ń darí láti lọ wo ohun tó wáyé níbẹ̀ .

“Ọ̀gá àgbà Fásitì pàṣẹ pé kí gbogbo ẹ̀ka ìlera tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ sáà akitiyan wọn láti dóòlà ẹ̀mí Olawuyi ṣùgbọ́n pàbó ló jásí.

“Ìsẹ̀lẹ̀ yìí ló fà á tí a fi gba ẹ̀mí ẹranko kìnìnú ọ̀hún.

“Olawuyi tí ń tọjú àwọn kìnìnú yìí láti ọdún mésàn án sẹ́yìn ṣùgbọ́n ó bani lọ́kàn jẹ́ pé kininu náà ṣekúpa ẹni tó ti ń fún wọn ní oúnjẹ jẹ.

“ Àwọn aláṣẹ Fásitì ti ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn sí àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé, tó sì rọ̀ wọ́n láti gbà pé àmúwá Ọlọ́run ni.”

Olarewaju wá fikun pé Ọ̀gá Fásitì ti pàṣẹ pé kí ìwádìí lórí ohun tó ṣokùnfa ikú Olabode Olawuyi bẹ̀rẹ̀ ní kíákíá .

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here