Bàbá ọmọdé, bàbá àgbà, èèyàn ńlá ni Jimi Solanke tó di olóògbé’

‘Bàbá ọmọdé, bàbá àgbà, èèyàn ńlá ni Jimi Solanke tó di olóògbé’

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwáyé è kú kan kò sí, ayé lọjà, ọ̀run yìí nibùgbé fún kóówá.
Ìràwọ̀ nlá já lókè erin ṣubú lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Kejì, ọdún 2024, bí àgbà olukọtan, asọ̀tàn, olórin ìbílẹ̀, akéwì tó tún jẹ́ àgbà òṣèré, Alàgbà Jimi Solanke ṣe dáṣọrọ̀gún lẹ́ni ọdún méjìlélọ́gọ́rin.
Lásìkò tó ń bá akọ̀ròyìn sọrọ níi Ilé olóògbé tó wà nílùú Ipara, ní ìpínlẹ̀ Ògùn, ìyàwó rẹ̀, Oluwatoyin Sename, sọ pé Ọmọ Ọlọ́run ni òun má ń pe ọkọ òun, nítorí pé inú rẹ̀ mọ́, ẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run ni, tí kìí fẹ́ se nǹkan tí kò tọ .

“Mi ò lè sọ bí ikú rẹ̀ ṣe rí ní ara mi, nítorí pé alájọrò mi ni.

“ Ọlọ́run nìkan ni mo ń wò lójú báyìí, nítorí pé Jimi ni ọlọ́rọ̀ kan ṣoṣo tí mo ní.”

Bákan náà ọba ìlú Iapara, Ọba Taiwo Taiwo sọ pé Bàbá Amúlùúdùn ìlú Ipara ló jẹ́.

Ọba Taiwo sọ pé Bàbá tó gbé ògo ìlú náà ga ni Solanke jẹ́ nígbà ayé rẹ̀.

Ó ní àwọn nǹkan tí olóògbé ṣe sí ìlú Ipara, kò ṣe é fi ẹnu sọ tán.

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀kan lára àwọn ọmọ olóògbé, Tioluwalope Atoyebi sọ fún akọroyin pé, bàbá tó mọ iyì ọmọ títí di ọjọ́ ikú ni.

“ Lóòótọ́ ni mo ti lọ sílé ọkọ, àmọ́ bàbá mi ṣì má a ń se mi bí ẹni pé mo ṣì wà lábẹ́ wọn.”

Àwọn ẹbí olóògbé Jimi Solanke sọ pé ẹni tí orúkọ rẹ̀ kò lè parun láíláí ni, nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ìran yìí àti ìran tó ń bọ̀ ni yóó sì lo àwọn iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìwádìí ìmọ ìjìnlẹ̀ wọn.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ tó wo àwọn eré orí ìtàgé bíi Kurunmi àti Ovonramwen Nogbaisi tí Ola Rotimi kọ, Death and the King’s Horseman ti Wole Soyinka kọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n mọ pé gbagada ni ojú Jimi solanke wà nínú àwọn eré náà torí òun ni ó kó ipa tó tóbi jùlọ nínú wọn.

Ó ti lé ní àádọ́ta ọdún tó ti lò nínu iṣẹ́ tíátà nípa gbígbé àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá àti agbègbè rẹ̀ ga.

Ìlú Èkó ni wọ́n bí Solanke sí ní ọdún 1942.

Ní ẹ̀ka ti orin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ orin àti orin ìtàn ni Bàbá Solanke ti kọ àti èyí tí kò tilẹ̀ tíì gbé jáde rárá rárá.

Àwọn orin ọmọdé náà kò gbẹ́yìn níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun bàbá Solanke ṣi ṣe n dán kooroko nínú orin yìí

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here