Ọ̀gbẹ́ni Ọláwuyì tí Kìnìún gbẹ̀mí rẹ gbakú oníkúkú ni—-Alukoro

Ọ̀gbẹ́ni Ọláwuyì tí Kìnìún gbẹ̀mí rẹ gbakú oníkúkú ni—-Alukoro

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Ní ọjọ́ Ajé Mọ́ńdè, ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kejì Ọdún 2024. Ni ìròyìn ikú ọkùnrin akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú ìmọ̀ títọ́jú ẹranko lọ́nà ìgbàlódé (Veterinary Technologist) ní Fásitì ifẹ̀, ẹni tí ọ̀kan lára àwọn Kìnìún tó ń fún lóúnjẹ gbẹ̀mí rẹ̀.

Olóògbé ti lo ogún ọdún níbi iṣẹ́, ó sì ti lé ọdún mẹ́wàá tí Olóògbé Ọlábọ̀dé Ọláwuyì ti ń ṣàkóso ọgbà tí wọ́n ń kó àwọn ẹranko pamọ́ ṣe lọ́jọ̀ sí nínú Fásitì ilé ifè.

Lọ́sàn-án ọjọ́ Mọnde, ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ lásìkò tọ́kùnrin olóògbé náà ń fún Kìnìún kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lóúnjẹ nínú ọgbà Fásitì ilé ifẹ̀. Lójijì ni kìnìún ọ̀hún pajúdà si olóògbé, tó sì fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.

Alukoro Fásitì Ọbáfẹ́mi Awólówò nílùú Ilé-Ifè Abíọ́dún Ọlárenwájú ṣọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣokùnfà ikú Olóògbé Ọlábọ̀dé Ọláwuyì ẹni tí Kìnìún pa jẹ́ ìbànújẹ ọkàn fún gbogbo òṣìṣẹ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì náà.

Ó ní ikú oníkú ni Olóògbé Ọlábọ̀dé Ọláwuyì gbà kú, látàrí pé kìí ṣe Olóògbé Ọlábọ̀dé Ọláwuyì ni Kìnìún náà dojú ìjà kọ.
Ó ní Arábìnrin kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ inú ọgbà ẹranko ni Kìnìún náà dojú ìjà kọ. Èyí ni olóògbé rí tó mú kí Olóògbé tiraka láti gba Arábìnrin náà sílẹ̀ lọ́wọ́ Kìnìún náà, àmọ́ lójú ẹsẹ̀ ni Kìnìún náà pa ojú dà sí Olóògbé Ọlábọ̀dé Ọláwuyì tó sì pa á pátápátá.

Alukoro Abíọ́dún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ṣàlàyé pé àwọn òṣìṣẹ́ méjèèjì kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa fún Kìnìún náà lóúnjẹ ṣùgbọ́n, ìlẹ̀kùn kan ni kò tìì tán lákòkó tí wọ́n fún Kìnìún náà lóúnjẹ ló fi ráyè láti já.

Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ Fásitì Ọbáfẹ́mi Awólówò, ti sọ kọ́kọ́rọ́ sí gbàgede ọgbà ẹranko tó wà ní ọgbà ilé
ẹkọ náà lẹ́yìn tí kìnìún náà ṣekúpa ẹni tí ó ń tọ́jú rẹ̀.

Alukoro Abíọ́dún Ọlárenwájú ní àwọn ń dúró de ẹbí Olóògbé Ọlábọ̀dé Ọláwuyì láti mú ọjọ́ tí wọn yóò ṣe ètò ìsìnkú Olóògbé náà.

Àwọn akọ̀ròyìn tó lọ síbi ìkẹ́dùn náà ní ojú ìjà ni àwọn ẹbí olóògbé náà gbé pàdé wọn nígbà tí àwọn fẹ́ gba ọ̀rọ̀ sílẹ̀ lẹ́nu won. Wọn kò fi ààyè sílẹ̀ fún ohunkóhun rárá.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here