Kà nípa nǹkan tí o nílò láti jàǹfàní ẹ̀yáwó ₦200bn tí ìjọba fẹ́ pín f’áwọn òǹtàjà

Kà nípa nǹkan tí o nílò láti jàǹfàní ẹ̀yáwó ₦200bn tí ìjọba fẹ́ pín f’áwọn òǹtàjà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí orí bá ń ta àwọn èèyàn àwùjọ kan, bí ìjọba orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ ò bá sánjú pin, yóò máa wá ọ̀nà àbáyo sí ìpọ́njú wọn.

Ní báyìí,ilé ìfowópamọ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ okoòwò ní Nàìjíríà ìyẹn Bank of Industry (BOI) ti ní àwọn fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní pín ẹ̀yáwó oní ipele mẹ́ta fún àwọn ọlọ́jà àtí olókoòwò káàkiri Nàìjíríà.

Wọ́n ní owó náà ni iye rẹ̀ tó igba bílíọ̀nù náírà láti fi ṣe àtìlẹyìn fún àwọn okoòwò kéékèèkèé láti fi mú ìgbèrú bá ètò ọrọ̀ ajé.

Àtẹ̀jáde kan tí ilé ìfowópamọ́ náà fi léde ní ẹ̀yáwó náà ni yóò ní ipele owó ìrànwọ́ ti ìjọba àpapọ̀ ń fún àwọn ènìyàn, ètò ìbojú àánú wo àwọn okoòwò kéréje àti ṣíṣe àtìlẹyìn fún àwọn iléeṣẹ́ tó ń pèsè ọjà ní Nàìjíríà.

Adarí ilé ìfowópamọ́ BOI, Olasupo Olusi nínú àtẹ̀jáde náà ní àádọ́ta bílíọ̀nù náírà nínú owó náà ló wà fún ṣíṣe àtìléyìn fún àwọn olọ́jà kéréje.

Ó ní ó kéré tán, àwọn obìnrin àti ọ̀dọ́ tí iye wọ́n tó ẹgbẹ̀rún kan káàkiri ìjọba ìbílẹ̀ 774 tó wà ní Nàìjíríà ni yóò jẹ àǹfàní yìí.

Ó ní àwọn ọlọ́jà tí yóò gba ìrànwọ́ ní ipele yìí ni àwọn olóúnjẹ, àwọn oníṣẹ́ ọwọ́, àwọn ọlọ́kọ̀, àwọn oníṣẹ́ ọnà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ó fi kun pé àwọn tó bá gba owó ìpele yìí kò ní da owó náà padà.

*Ìgbésẹ àti rí owó náà gbà*

Kí ènìyàn tó lè ní àǹfàní sí owó yìí, ó gbọ́dọ̀ ní ọjà tàbí iṣẹ́ ọwọ́ kan tí ò ń ṣe
O gbọ́dọ̀ ṣetán láti ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ ọjà àti okoòwò rẹ.
O gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ènìyàn mọ́ra láti máa bá ọ ṣiṣẹ́ tí ọjà náà bá gbèrú si
O gbọ́dọ̀ fi ẹ̀rí pé ò ń gbé ní agbègbè kan ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Nàìjíríà múlẹ̀
Bákan náà ni o gbọ́dọ̀ ní fi akoto owó pẹ̀lú ilé ìfowópamọ́ báǹkì kan sílẹ̀
Kò pọn dandan láti pèsè nọ́mbà ìdánimọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà tàbí ti BVN
Ó gbọ́dọ̀ fi orúkọ sílẹ̀ fí àǹfàní yìí kí ọjọ́ tí wọ́n gbé kalẹ̀ fun tó wá sópin
Ipele kejì ni àwọn oní iléeṣẹ́ kékeré, tí ilé ìfowópamọ́ BOI sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé bílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́rin náírà ni wọ́n ti yà kalẹ̀ fún èyí.

Wọ́n ní owó náà yóò jẹ́ ìrànwọ́ fún àwọn iléeṣẹ́ yìí láti mú àdínkù bá ìṣòro tí wọ́n ń kojú lórí pípèsè àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe àti láti gbé ọjà wọn láti ibìkan lọ sí òmíràn.

Wọ́n fi kun pé ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn tó máa jẹ àǹfàní yìí ni yóò gba mílíọ̀nù kan náírà àti pé ìdá mẹ́sàn-án ni àlékún tí yóò gorí owó náà tí wọ́n bá fẹ́ da padà.

Bákan náà ni wọ́n fi kun pé àwọn iléeṣẹ́ ńlá tó ń pèsè ọjà náà ni àwọn máa fún ní ẹ̀yáwó bílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́rin láti fi mú àdínkù tí wọ́n ń kojú lẹ́nu iṣẹ́ wọn.

Bílíọ̀nù kan náírà ni àwọn tí yóò jẹ àǹfàní yìí máa gbà pẹ̀lú àlékún ìdá mẹ́sàn-án tí wọ́n máa dá padà láàárín ọdún márùn-ún.

Ìpèsè ẹ̀yáwó yìí ló ń wáyé látọwọ́ ìjọba àpapọ̀ láti mú àdínkù bá ìṣòro tí àwọn èèyàn ń kojú pàápàá jùlọ bí ètò okoòwò ṣe rí lásìkò yìí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here