Gómìnà Seyi Mákindé ṣàlàyé ohun tó fa ìbúgbàmù ní Ìbàdàn

Gómìnà Seyi Mákindé ṣàlàyé ohun tó fa ìbúgbàmù ní Ìbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọn ní olè ò ní-ín jàgbà kó má ṣe é lójú fìrí, bẹ́ẹ̀ ojúlówó ọmọ onílùú kò ní fẹ́ ó tú.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí nígbà tí Mákindé ṣe àbẹ̀wò síbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù náà ti wáyé, bó ṣe ṣàpèwúye ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún gẹ́gẹ́ bí èyí tó ba ni lọ́kàn jẹ́ nítorí ó mú ẹ̀mí lọ.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣàlàyé pé ìwádìí ti fihàn pé àdó olóró táwọn èèyàn kan tó ń wa kùsà lọ́nà àìtọ́ kó pamọ́ síbì kan ló ṣokùnfa ìbúgbàmù náà.

Mákindé ní ìwádìí sì ń lọ lọ́wọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún, àmọ́ gbogbo ẹni tó bá wà nídìí ìbúgbàmù yìí ni yóó fojú winá òfin.

‘’Lẹ́sẹ̀ kẹsẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́ adóòlà ẹ̀mí ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti lọ síbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ àṣekára .

Wọ́n ṣiṣẹ́ láti alẹ́ di àárọ̀ Ọjọ́rùú ni, oríṣìíríṣìí irinṣẹ́ ìdóòlà ẹ̀mí, ọkọ̀ ańbúláǹsì àtàwọn ẹ̀ṣọ́ elétò ló ti wà níbẹ̀.

Ní báyìí, èèyàn mẹ́tàdín lọ́gọ́rin ló farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún, àmọ́, wọ́n ti gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn, wọ́n sì ti padà sílé wọn.

Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé èèyàn méjì ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún lọ, kí Ọlọ́run tẹ́ wọn sí afẹ́fẹ́ rere kí Ó sì tu àwọn ẹbí wọn nínú.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni yóó san owó ìtọ́jú àwọn èèyàn tí wọ́n ṣèṣe níbi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.

Ìjọba tún máa pèsè ilégbèé fáwọn tí kò nílé lórí mọ́ látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí,’’ Mákindé ló sọ bẹ́ẹ̀.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wá rọ gbogbo àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti pé nọ́ńbà 615 fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, nígbà tí ó tún rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n farabalẹ̀ àti pé kí wọ́n jìnà sí ibi tí ìbúgbàmù náà ti wáyé, káwọn òṣìṣẹ́ adóòlà ẹ̀mí lè ráyè ṣiṣẹ́ wọn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here