KebeN’Kwara Kollington Ayinla wà lọ́sibítù lórí àìsàn tó lè koko
Fẹ́mi Akínṣọlá
Lásìkò yìí, inú ìbẹ̀rù àti ìpayà ọkàn gidi ni àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn olólùfẹ́ èèkàn olórin Fújì nnì, Alaaji Kọllington Ayinla, táwọn èèyàn mọ̀ sí KebeN’Kwara wà látàrí bí àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí kan ṣe dá a gbálẹ̀, ipò tó le koko ló sì wà lọ́sibítù ìjọba báyìí, níbi tí wọ́n ti ń tọjú àwọn tí àìsàn wọ́n le gidi, wọ́n lọ́kùnrin náà kò lè sọ̀rọ̀ mọ́, afẹ́fẹ́ oxygen ni wọ́n fi rọ́bà fà sí i nínú tó fi ń mi.
Òun tí a gbọ́ ni pé nǹkan bíi àṣálẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta, Sátidé, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Kínní ọdún 2024 ni àárẹ̀ ọ̀hún fẹ́ gbòdì lára bàbá náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni Kebe, Bàbá Alágbàdo, gẹ́gẹ́ bó ṣe pé ara rẹ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn rẹ́kọ̀ọ̀dù rẹ̀, tí ń bá àìsàn ìtọ̀ ṣúgà àti àìlera kíndìnrín fínra.
Lálẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sáré gbé e dìgbàdìgbà lọ síléèwòsàn aládàáni kan, ní agbègbè Alákùkọ, ti kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ilé rẹ̀ ní Alágbàdo, ìpínlẹ̀ Èkó. Wọ́n ní mí-mí ọkùnrin náà ti di gule-gule, gbogbo nǹkan sì ti fẹ́ dojú rú nígbà tí yóó fi délé-ìwòsàn, èyí ló fà á tí wọ́n fi tètè gbé ẹ̀rọ téèyàn fi ń mí pẹ̀lú atẹ́gùn oxygen sí i lára, láti dóòlà ẹ̀mí rẹ̀.
Lẹ́yìn àsìkò díẹ̀, ni àwọn dókítà ilé ìwòsàn aládàáni ọ̀hún kọ̀wé pé kí wọ́n tètè máa gbé Kollington Ayinla lọ ilé ìwòsàn Jẹ́nẹ́rà tó wà n’Íkẹjà, fún ìtọ́jú tó péyé . Ọsibítù náà sì ló wà títí di bá a ṣe ń sọ yìí.
A gbọ́ pé níṣe ni ẹsẹ̀ àgbà ọ̀jẹ̀ onífújì yìí wú rọbọtọ, tí wíwú náà kò sì rọlẹ̀ rárá. Yàtọ̀ sí àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ìyẹn dayabẹ́tììsì àti àìlera kíndìnrín tí iṣẹ́ rẹ̀ kò péye tó, àwọn tí wọ́n sún mọ́ bàbá náà sọ pé ó tún ní àìsàn ọgbẹ́-inú , ulcer, torí ìdí èyí ni kì í ṣe fi oúnjẹ ṣeré rárá, àmọ́ lásìkò yìí, wọ́n ní bàbá náà kò tiẹ̀ lajú, tàbí sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò lè jẹun, àfi èyí tí wọ́n ń fi ẹ̀rọ fà á sí i lára.
Ṣá, ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ti wọlé àdúrà fun Kollington, ẹni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́rin (74), tí wọ́n sì n bẹ Ọlọ́run kó dáwọ́ lé e, kí ara rẹ̀ lè mókun padà.Bẹ́ẹ̀ làwọn onífújì ẹlẹ́gbẹ rẹ̀ náà ti dìde ìrànwọ́ àti àtìlẹ́yìn fún un.
Ẹ ó rántí pé fún ọ̀pọ̀ ọdún ni Alaaji Kọllington Ayinla àti ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ rẹ̀, Alaaji Sikiru Ayinde Barrister tó dolóògbé lọ́jọ́sí fi léwájú nídìí iṣẹ́ orin Fújì, tí wọ́n sì jọ figagbágba gidi, títí tí wọ́n fi gbé ògo iṣẹ́ náà dé ìlú òyìnbó, tí wọ́n fi di ìlúmọ̀-ọ́n-ká.
Ọ̀pọ̀ rẹ́kọ̀ọ̀dù àti eré ni bàbá náà ṣe, àkàákàtán sì ni eré òde àti oyè tí wọ́n fi dá a lọ́lá.