Òkú Gómìnà Akeredolu balẹ̀ sí Nàìjíríà láti òkè òkun
Fẹ́mi Akínṣọlá
Kò sí ohun náà láyé tí òpin kò ní-ín dé bá. Àìsí mọ́ lòpin èèyàn, bí ó ti jẹ́ pé òkú Gómìnà télẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, Arákùnrin Oluwarotimi Akérédolú ti balẹ̀ sí orílẹ-èdè Nàìjíríà.
Ọkọ̀ bàálù tó gbé òkú náà balẹ̀ ní déédé aago mẹ́ta àbọ̀ ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kínní ọdún 2024.
Láti orílẹ-èdè Germany ni wọ́n ti gbé òkú náà wá sí orílẹ-èdè Nàìjíríà,
Ìyàwó Gómìnà tẹ́lẹ̀, Betty Anyanwu-Akeredolu, àwọn ọmọ àti mọ̀lẹ́bí tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Akérédolú léwájú fún ló lọ pàdé òkú náà.
Lára àwọn tó wà pẹ̀lú wọn ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwoolu, ẹni tí ọ̀gá àgbà fún òsìsẹ́ , Tayo Ayinde sojú, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, Dapo Abiodun, ẹni tí Akọ̀wé ìjọba ní ìpínlẹ̀ Ògùn, Tokunbo Talabi sojú fún un pẹ̀lú.
Àwọn yòókù ni alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Òǹdó,Ade Adetimehin, ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, Gboyega Adefarati, àwọn ìgbìmọ̀ ìjọba ẹni tí akọ̀wé ìjọba, Ọmọọba Oladunni léwájú fún wà pẹ̀lú àwọn tó tẹ́wọ́gba òkú náà.
Omijé bó ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ lásìkò tí wọ́n gbé òkú náà kalẹ̀ láti ínú bàálù.
Gómìnà Akérédolú jáde láyé ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2023 nílùú Germany.
Wọ́n yóò gbé òkú rẹ̀ sí ilé ìgbé òkú sí títí ètò ìsìnkú yóó fi wáyé