Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ikọ̀ ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ adigunjalè ẹlẹ́ni márùn-ún kan
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní ọjọ́ gbogbo ni tolè, ọjọ́ kan péré ni ti olóhun.
Ọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá agbègbè Kurmi, ní ìjọba ìbílẹ̀ Bakori, ní ìpínlẹ̀ Katsina, làwọn ikọ adigunjale ẹlẹni márùn-ún kan tí wọ́n máa ń fìgbà gbogbo dààmú àwọn aráàlú náà wà báyìí. Àwọn tọwọ ti tẹ ni Ọgbẹni Sharhabilu Dahiru, ẹni ogún ọdún, Ọgbẹni Abubakar Tukur, ẹni ọdún mẹẹẹdọgbọn, Ọgbẹni Kasamanu Abdullah, ẹni ogún ọdún, Ọgbẹni Abdul Rahman Shu’aibu, ẹni ogún ọdún, àti Ọgbẹni Suleiman Sanusi, ẹni ogún ọdún. Ẹsùn tí wọ́n fi kan gbogbo wọn pátá ni pé wọ́n níbọn ìléwọ àgbélẹrọ lọwọ́ tí wọ́n fi máa ń ja àwọn aráàlú lólè nígbà gbogbo.
Oun tí a gbọ́ ni pé ọjọ́ pẹ́
táwọn ikọ̀ ẹlẹ́ni márùn-ún ọ̀hún ti ń lọ káàkiri ìgboro, pàápàá jù lọ lágbègbè Kakumi, ní ìjọba ìbílẹ̀ Bakori yìí kan náà, tí wọ́n sì máa ń jà wọn lólè, kọ́wọ́ tóó tẹ̀ wọ́n láìpẹ́ yìí.
Alukoro ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, A.S.P Abubakar Sadiq Aliyu, tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ ọhún múlẹ̀ fáwọn oníròyìn l’Ọ́jọ́rùú, ogúnjọ́, oṣù Kejìlá, ọdún yìí, sọ pé òwúyẹ kan ló wáá ta àwọn ọlọ́pàá agbègbè náà lólobó lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù Kejìlá, ọdún yìí, táwọn sì lọ fọwọ́ òfin mú gbogbo wọn pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọdẹ àdúgbò.
Lára àwọn ohun ìjà olóró táwọn ọlọ́pàá gbà lọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn ọ̀hún ni ìbọn AK-47 àtàwọn ohun ìjà olóró mìíràn.
Síwájú sí i, alukoro ní lójú-ẹsẹ̀ táwọn ti fọwọ́ òfin gba gbogbo wọn mú ni wọ́n ti jẹ́wọ́ fáwọn agbófinró pé lóòótọ́ làwọn máa ń lọ káàkiri ìlú láti ja àwọn èèyàn lólè.
Wọ́n láwọn máa tó parí ìwádìí nípa wọn, táwọn sì máa fojú gbogbo wọn balé-ẹjọ́, kí wọ́n lè fimú káta òfin.