Ẹ̀wọ̀n n rùn lóríi ọkùnrin yìí’ físà sílùú òyìnbó ló fi n lu jìbìtì l’Akurẹ

Ẹ̀wọ̀n n rùn lóríi ọkùnrin yìí’ físà sílùú òyìnbó ló fi n lu jìbìtì l’Akurẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí èèyàn bá n yọ́lẹ̀ ẹ́ dà, ohun aburú á máa yọ́wọn ṣe.

Ilé-ẹjọ́ Májísírètì kan tó fìkàlẹ̀ sílùú Akurẹ, ti ní kí baba àgbàlagbà kan, Daniel Adedọtun, ṣì lọ máa gbatẹ́gùn nínú ọgbà àtúnrọ ìwà tó wà ní Olokuta, lórí ẹ̀sùn fífi físà gbígbà lu ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ní jìbìtì.

Bàbá ẹni ọdún mẹtalelọgọta ọ̀hún àtàwọn mí-ìn táwọn ọlọ́pàá ṣì ń wá báyìí ni wọ́n fẹsun kàn pé wọ́n fi ẹ̀tàn gba owó tó dín díẹ̀ ní mílíọ̀nù lọnà ogun Náírà (#19.7m) lọwọ́ àwọn èèyàn kan nílùú Akurẹ, lórí ọrọ̀ pé wọ́n fẹ́ bá wọn gba fisa ìlú òyìnbó laarin oṣu Kejì si Ikẹwaa, ọdun yii.

Lára ẹsùn mẹ́fà tí wọ́n kà sí bàbá yìí lọ́rùn nígbà tó ń fara hàn níwájú Onídàájọ Damilọla Ṣekoni, lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejìlélógún, oṣù Kejìlá yìí, ni ìgbìmọ̀-pọ̀ hùwà tó lòdì sófin, olè jíjà, fífi ọ̀nà èrú sọ nnkan oní nnkan di tẹni, fífi ẹ̀tàn gbowó lọ́wọ́ ẹni àti jìbìtì lílù.

Àwọn ẹ̀sùn yìí ni ọlọ́pàá agbèfọ́ba, Simon Wada, ní ó ta ko abala kín-ín-ní, ìlà kín-ín-ní àti ẹ̀kẹta, okoòlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ́ta dín mẹ́rin (516) nínú ìwé òfin ìpínlẹ̀ Ondo ti ọdún 2006.

Wada ní owó tó tó mílíọ̀nù mẹ́sàn-án Náírà ni afurasí ọ̀hún fẹ̀tàn gbà lọ́wọ́ ọkùnrin kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fọlayẹle, pẹ̀lú ìlérí pé òun fẹ́ ràn án lọ́wọ́ láti gba ìwé-ẹ̀rí tí yóó fi kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Jìbìtì mílíọ̀nù méje Náírà ni Abilékọ kan tí wọ́n porúkọ rẹ̀ ní Christianah Jombo, fi gbára ní tirẹ̀, èyí tó san fún afuarsí oníjìbìtì yìí láti bá a fi gba físà Amẹ́ríkà fún àbúrò rẹ̀ kan, Abilékọ Aderonkẹ Ayangbemi. Bẹ́ẹ̀ ló tún fọ̀nà èrú gba mílíọ̀nù márùn-ún àtààbọ̀ Náírà lọ́wọ́ Fẹmi Bayọde, lórí ọ̀rọ̀ ìlú òyìnbó yìí kan náà.

Níparí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Wada ní òun fẹ́ kílé ẹjọ́ ṣì fi olùjẹ́jọ́ náà pamọ́ sọ̀gbá ìtúnirọ títí dìgbà tí ìmọràn yóò fi wá láti ọ́fììsì àjọ tó ń gba adájọ́ nímọ̀ràn.

Nígbà tó ń gbé ìpinnu rẹ̀ kalẹ̀, Onídàájọ Ṣekoni gba ẹ̀bẹ̀ agbèfọ́ba wọlé, lẹ́yìn èyí ló sún ìgbẹ́jọ́ mí-ìn sí ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kín-ín-ní, ọdún 2024

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here