Àwọn ọmọ ìsọta da ọkọ̀ tó ń gbé oúnjẹ ọdún lọ sí ààfin Olúbàdàn lọ́nà, wọ́n pín-in m’ọ́wọ́

Àwọn ọmọ ìsọta da ọkọ̀ tó ń gbé oúnjẹ ọdún lọ sí ààfin Olúbàdàn lọ́nà, wọ́n pín-in m’ọ́wọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní kéreré la tií pẹ̀ka ìrókò, bó bá dà
gbà tán, ẹbọ nlá ni yóó máa gbà.
Ó jọ pé àwọn jàǹdùkú ìgboro Ìbàdàn kò fẹ́ rí oúnjẹ tútù tí wọ́n ń gbé kọjá lọ nínú mọ́tò sójú mọ́ báyìí pẹ̀lú bí àwọn ọmọ ìṣọta kan ṣe tún dá ọkọ̀ bọ́ọ̀sì kan tó ń gbé oúnjẹ tútù lọ sáàfin Olúbàdàn lọ́nà, tí wọ́n sì pín oúnjẹ inú ẹ̀ mọ́ra wọn lọ́wọ́.

Ọkọ̀ bọ́ọ̀sì ọ̀hún, tó kún fún àpò ìrẹṣì, ààyè adìẹ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ́ẹ̀gì òróró, èyí tí wọ́n ń gbé lọ sáàfin Olúbàdàn tó wà lỌ́jà’ba, n’Ibadan, làwọn ọmọ ìṣọta náà da lọ́nà, tí wọ́n sì bo àwọn oúnjẹ inú ẹ̀ bíi ìgbà tí àwọn adìẹ bá bo ọkàabàbà tó dá sílẹ̀ nígbà tó kù díẹ̀ kí ọkọ̀ ọ̀hún, tó ń bọ̀ láti ọ̀nà Mapo, n’Ibadan, dé ààfin Olúbàdàn ọ̀hún.

Gẹ́gẹ́ báa ṣe gbọ́, oúnjẹ tí wọ́n fẹ́ pin fáwọn Mọ́gàjí ìlú Ìbàdàn gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀bùn ọdún làwọn ọmọ ayé ṣe bẹ́ẹ̀ pín mọ́ra wọn lọ́wọ́ lọ́sàn-án gangan Ọjọ́bọ, ọjọ́ kọkànlélógún (21), oṣù Kejìlá, ọdún 2023 yìí.

Níṣe ni wọ́n fọ́ gbogbo gíláàsì ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀ náà ki wọ́n lè ríbi kó gbogbo oúnjẹ tó wà nínú ẹ̀.

Tẹ́ ò bá gbàgbé, ní nǹkan bíi oṣù Méjì sẹ́yìn làwọn èèyàn ya bo ọkọ̀ kan tó ń gbé ìrẹsì kọjá lọ lágbègbè Iwo Road, n’Ibadan, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i pín àwọn àpò ìrẹsì náà mọ́ ara wọn lọ́wọ́ kó tóó di pé dẹ́rẹ́bà tó wakọ̀ náà ṣíná fún ọkọ̀, tó sì ṣá lọ mọ́ wọn lọ́wọ́.

Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀, ọkàn nínú àwọn Mọ́gàjí ilẹ̀ Ìbàdàn, Mọ́gàjí Nurudeen Akinade, ẹni tó wà nínú ọkọ̀ tó gbé oúnjẹ náà lásìkò ìkọlù ọ̀hún ṣàlàyé pé méjìlá nínú àwọn ọmọ gànfe ọ̀hún lọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ̀ báyìí, nítorí loju-ẹsẹ tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọhún ti wáyé làwọn ti lọ fi tó wọn létí ní téṣàn ọlọ́pàá tó wà ní Mapo, n’Ibadan.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, “látìgbà tá a ti fi ìṣẹlẹ̀ yẹn tó àwọn ọlọ́pàá létí ni wọ́n ti mú díẹ̀ nínú àwọn afurasí olè náà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ti rí díẹ̀ nínú wọn mú lónìí náà. Àwọn tọ́wọ́ ti tẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ṣáà ti di méjìlá bí mo ṣe ń bá yín sọ̀rọ̀ yìí ”.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here