Nǹkan dé ! Portable ati Pasuma ti di ìṣòro fún ṣọọsi ṣẹ̀lẹ
Fẹ́mi Akínṣọlá
Túláàsì ní òhun yóó jókòó, ẹnìkan ní kò sáyè,bíí ṣe igiimú onítọ̀ún…..
Àfi bíi ẹni pé àṣà tí gbajúgbajà òǹkọrin hípọọ̀pù nnì, Habeeb Okikiọla Ọlalọmi, táwọn èèyàn mọ̀ sí Portable olórin , máa ń dá, tó máa ń sọ pé, “wàhálà, wàhálà, wàhálà” ti ṣẹ sí i lára ni, látàrí bí ọkan-o-jọkan awuyewuye ṣe ń ṣẹlẹ̀ láwọn ibi tí ọkùnrin táwọn ọdọ fẹ́ràn orin rẹ̀ náà bá lọ. Tuntun tó ṣẹlẹ̀ báyìí ni awuyeyewu tó ń lọ láàrin àwọn wòlíì àti adarí ṣọọṣi Ṣẹ̀lẹ́, látàrí bí Portable àti Wasiu Alabi Pasuma, Ọganla onífújì, ṣe lọ kọrin níbi ayẹyẹ àṣálẹ́ ìyìn ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀hún kan. Èyí bi àwọn àgbààgbà ìjọ náà nínú gidigidi.
Ètò ìjọsìn ọ̀hún ti wọ́n pè ní Ankara/Praise Night, ló wáyé lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, oṣù Kejìlá yíì, nínú ṣọ́ọ̀ṣì Sẹ̀lẹ́ Land of Goshen Cathedral, lágbègbè Ogudu/Ọjọta, l’Ekoo, níbi tí wọ́n ti fìwé pe Portable, tó tún máa ń pe ará ẹ̀ ní Ìdààmú Àdúgbò, àti Pasuma sí.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan, àti àwọn adarí ìjọ Ṣẹ̀lẹ́ kan korò ojú sí bí wọ́n ṣe pe àwọn tí kì í ṣe olórin ẹ̀mí síbi ètò ìjọsìn yìí, tí wọ́n sì kìlọ̀ gidigidi fún Portable láti má ṣe yọjú síbi ètò náà, àmọ́ Portable ati Pasuma lọ. Sùtánà Sẹ̀lẹ́ funfun kinniwin ni Portable wọ̀, àwọn méjéèjì sì kọrin gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe lóde àríyá, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn náwó fún wọn, táwọn olólùfẹ́ wọ́n sì dárayá gidi.
Èyí ló fa wàhálà báyìí, nítorí ọ̀rọ̀ náà kò dùn mọ́ àwọn àgbààgbà tí Olùdarí ẹsìn ọhún kan nínú, tí wọn si ti n sọ̀kò ọ̀rọ̀ síra wọn.
Nínú fídíò kan tó bọ́ sórí ẹ̀rọ ayélujára lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kejìlá yìí, Olùdarí ṣọ́ọ̀ṣì Sẹ̀lẹ́ kan, Wòlíì Tayọ Ọkẹ, fi àìdùnnú rẹ̀ hàn sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó ní nǹkan àbùku àti ìtìjú pátápátá gbáà ni báwọn olórin wọ̀nyí ṣe wáá ṣeré ní ṣọ́ọ̀ṣì àwọn, ó ní irú nǹkan báyìí kò wáyé nínú àwọn ìjọ Ọlọ́run tó dé lẹ́yìn Sẹ̀lẹ́, bíi Rìdíìmù, Àpọ́sítólíkì àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì mí-ìn.