Iná jólé Alao Akala, ẹ̀mí èèyàn kan bá a lọ

Iná jólé Alao Akala ní ẹ̀mí èèyàn kan bá a lọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ní airotẹlẹ ni iná dédé ṣẹ́yọ nínú ọ̀kan lára àwọn ilé tó n bẹ nínú ọgbà Gómìnà tẹ́lẹ̀rí ní ìpìnlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olóògbé Ọ̀túnba Adebayọ Alao Akala l’ówùúrọ̀ ọjọ́ Ajé.

Ọ̀kan lára àwọn olùgbé ilé náà, tí a fi orúkọ bò l’áṣìírí, fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ fún akọ̀ròyìn pé ní nnkan bíi aago méje ààbọ̀ sí mẹ́jọ òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Olùgbé ilé náà ní, “Iná ẹ̀lẹ́ntíríìkì ló dé lójijì l’ówùúrọ̀ ọjọ́ náà tí ó sì jó ẹni kan. Ẹlòmíràn náà tún fi ara pa.”

Ṣùgbọ́n, ìròyìn kan tí a kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ sọ pé èèyàn méjì ló kú nínú iná tó jó ọ̀hún .

Bákan náà ni ìròyìn sọ pé obìnrin méjì ló jóna nínú ilé náà, àmọ́ àwọn aláṣẹ kò tíì fìdí èyí múlẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí iléṣẹ́ ìròyìn orí ayélujára “Ogbomoso Insight “ṣe sọ, inú ilé alájà kan ọhún ni Olóògbé Àlàó Akálà gbé títí tó fi di igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ́dún 2003.

Nínú oṣù kínní ọdún 2022 ni Ọ̀túnba Adébayọ̀ Àlàó-Akala jáde láyé.

Ó jẹ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láàrin ọdún 2007 sí 2011

Láti ìgbà tí Gómìnà tẹ́lẹ̀rí náà ti re ibi àgbà n rè gìrìgìrì ẹsẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ní ilé náà, kí ó tó di pé iná sọ níbẹ̀ l’ówùúrọ̀ ọjọ́ Ajé.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here