Akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ girama mẹ́fà rí ẹ̀wọ̀n he
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà sọ pé,ẹni bá ṣe ohun tẹ́nìkan ò ṣe rí, kò sí n tó burú, bí ojú u rẹ̀ bá rí n tẹ́nìkan ò rí. Àsamọ̀ yìí ló lọ pẹ̀lú bí à Nlwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ikú olùkọ́ wọn kan ní orílẹ̀ èdè France ti rí ẹ̀wọ̀n he.
Ní ọdún 2020 ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní orílẹ̀ èdè France níbi tí àwọn kan ti gé orí olùkọ́, Samuel Paty fẹ́sùn wí pé ó fi àwòrán ẹ̀fẹ̀ Ànọ́bì hàn ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́.
Ní ìwájú ilé ẹ̀kọ́ tó ti ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ ni wọ́n pa Paty sí.
Ilé ẹjọ́ ní ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ̀bi pé ó parọ́ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní kíláàsì gan-an, tí wọ́n sì ní àwọn yòókù jẹ̀bi ẹ̀sùn pé wọ́n tọ́ka Paty sí ẹni tó pa á.
Ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́rìnlá sí ọdún méjì ni ilé ẹjọ́ dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.
Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tó jẹ́ obìnrin ni wọ́n ní ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé Paty lé gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ mùsùlùmí kúrò ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ kó tó fi àwòrán náà hàn.
Àmọ́ ìwádìí ní ọmọbìnrin náà kò sí ní kíláàsì lọ́jọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé tí ilé ẹjọ́ sì ní ó jẹ̀bi irọ́ pípa àti pé ó sọ àwọn nǹkan tó da omi àláfíà rú.
Àwọm márùn-ún yòókù, tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́rìnlá sí mẹ́ẹ̀dógún lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ni ilé ẹjọ́ ní wọ́n jẹ̀bi pé wọ́n fi olùkọ́ náà sínú ewu.
Ẹni tó ṣekúpa olùkọ́ náà, Abdoullakh Anzorov, ọmọ ọdún méjìdínlógún ni àwọn ọlọ́pàá yìbọn pa lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà.