Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún Náírà ni mo ta orí àti ọwọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Ifẹ̀ – Akeem

Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún Náírà ni mo ta orí àti ọwọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Ifẹ̀ – Akeem

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹni bá hùwà kòtọ́, ó di dandan kó fojú winá òfin.
Ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá ní Eléwéeran, nílùú Abẹokuta, ìpínlẹ̀ Ògùn, ni Ọ̀gbẹ́ni Akeem Usman wà, níbi tó ti ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí ìwádìí tí wọ́n ń ṣe láti lè fọwọ́ òfin mú gbogbo àwọn oníbàárà rẹ̀ gbogbo tó ń ta àwọn ẹ̀yà ara òkú fún, ní pàtàkì , ti ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì ‘Ọbafẹmi Awolọwọ University’ (OAU) kan, Olóògbé Quadry Salami, tó dẹ́mìí rẹ̀ lẹ́gbòodò láìpẹ̀ yìí, tó sì ta àwọn ibi pàtàkì ẹ̀yà ara rẹ̀ fáwọn oníṣẹ́ ibi kan.

Ohun tí a gbọ́ ni pé Alàgbà Salami tí i ṣe bàbá Quadry ló lọ fẹjọ́ sun àwọn ọlọ́pàá agbègbè Kenta, nílùú Abẹokuta, lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Kọkànlá, ọdún 2023 yìí, pé òun ń wá ọmọ òun, Quadry, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ onípele àkọkọ́ 100 level nílé -ẹ̀kọ́ ‘Ọbafẹmi Awolọwọ University,’ (OAU). Bàbá náà ṣàlàyé fáwọn ọlọ́pàá pé láti ọjọ́ kẹjọ, oṣù Kọkànlá, ọdún yìí lòun ti fojú kàn án gbẹyin, ó lóun pe gbogbo fóònù rẹ̀, kò lọ, làwọn ọlọ́pàá bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, S.P Ọmọlọla Odutọla, tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fáwọn oníròyìn l’Ọ́jọ́rùú, ọjọ́ kẹfà, oṣù Kejìlá, sọ pé fúnra ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá ní ìpínlẹ̀ Ògùn, C.P Abiọdun Alamutu, ló ṣaájú ikọ̀ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ agbègbè ‘Mile 6’, tó wà nílùú Ajebọ, láti lọ fọwọ́ òfin mú Akeem Usman, lẹ́yìn ti òhun tí wọ́n fi n wá fóònù olóògbé náà tọ́ka sí i pé ọwọ́ rẹ̀ ló wà. Wọ́n gbá a mú, ó sì mú wọn lọ síbi tó sìnkú olóògbé náà sí.

Akeem yìí ló tọ́ka sí oníṣèègùn kan, Ọ̀gbẹ́ni Ifadowo Niyi, tó pé ní ọ̀rẹ̀ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò ló jẹ́wọ́ fáwọn ọlọ́pàá pé òun pẹ̀lú Ifadowo làwọn jọ pín ẹ̀yà ara olóògbé náà fún òògùn owó.

Alukoro ní, ‘‘Akeem ti jẹ́wọ́ fáwọn ọlọ́pàá, ohun tó sọ ni pé òun pẹ̀lú Ifadowo làwọn jọ pa olóògbé náà, táwọn sì pín ẹ̀yà ara rẹ̀, orí olóògbé náà àti ọrùn ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì ni Ifadowo kó lọ, ó sì san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún Náírà sínú àkáùǹtì Akeem.

‘‘Lẹ́yìn náà ni Akeem ń ta àwọn ẹ̀yà ara olóògbé náà lẹ́yọkọ̀ọ̀kan fáwọn èèyàn tó nílò rẹ̀ láti fi ṣòògùn Àwúre. Lópin ohun gbogbo, Akeem lọ ri ìyókù mọ́lẹ̀ nígbà tí kò wúlò fún un mọ́.

‘‘ Kódà àwọn méjèèjì ti tún jẹwọ́ fáwọn ọlọ́pàá pé kì í ṣe olóògbé yìí làwọn kọ́kọ́ pa, wọ́n ní àwọn ti fìgbà kan pa àwọn mẹ́rin kan sẹ́yìn, táwọn sì ti forí wọn ṣètùtù Oṣólẹ̀’’.

Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Alukoro ní ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá ní ìpínlẹ̀ Ògùn tí lóun kò ní í fojú tó dáa wo àwọn ọ̀daràn gbogbo tí wọ́n fẹ́ sọ ìpínlẹ̀ Ògùn di ibùgbé wọn, àfi kí wọ́n fi agbègbè ọhún sílẹ̀ ní kíá.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here