Ilé ẹjọ́ gíga pàṣẹ pé kí wọ́n fi Emefiele sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje

Ilé ẹjọ́ gíga pàṣẹ pé kí wọ́n fi Emefiele sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Abuja ti pàṣẹ pé kí wọ́n fi gómìnà àná fún ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN, Godwin Emefiele sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje títí ti wọ́n máa fi parí gbígba béèlì rẹ̀.

Ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu lásìkò tó wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà CBN ni Emefiele ń kojú.

Ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ló ti rí ìdádúró ní ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún ìdí kan tàbí òmíràn ṣùgbọ́n tó wáyé lọ́jọ́ Ẹtì.

Ẹ̀sùn ogún tí àpapọ̀ owó rẹ̀ jẹ́ bílíọ̀nù mẹ́fà lé ọwọ́ márùn-ún náírà ni ìjọba àpapọ̀ kọ́kọ́ kà sí Emefiele lọ́rùn láti kojú ìgbẹ́jọ́ lé lórí.

Àmọ́ ìjọba àpapọ̀ ti mú àdínkù bá iye ẹ̀sùn náà sí mẹ́fà tí owó rẹ̀ sì lé bílíọ̀nù kan náírà ní ilé ẹjọ́ lọ́jọ́ Ẹtì.

Agbẹjọ́rò Emefiele, Mathew Burkaa níbi ìgbẹ́jọ́ tó wáyé ní kí ilé ẹjọ́ fún Emefiele ní béèlì àmọ́ agbẹjọ́rò ìjọba, Rotimi Oyedepo kọ̀ jálẹ̀ pé wọn ò gbọdọ̀ fún ní béèlì.

Adájọ́ Hamza Muazu ní òun kò ní lè dájọ́ kankan lórí ìbéèrè náà látàrí bí àwọn agbẹjọ́rò méjéèjì ṣe gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀.

Adájọ́ ní òun nílò àkókó díẹ̀ láti fi ṣe àgbéyẹ̀wò ẹ̀rí tí agbẹjọ́rò Emefiele gbé wá sílé láti mọ̀ bóyá wọ́n máa fun ní béèlì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

Ó wá sún ìgbẹ́jọ́ lórí ọ̀rọ̀ béèlì Emefiele sí ọjọ́ Kejìlélógún oṣù Kejìlá, tó sì ní ìgbẹ́jọ́ lórí ẹjọ́ tó ń kojú gan-an.

Ó ní kí wọ́n fi Emefiele sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje títí tí wọ́n fi máa gbọ́ ẹjọ́ lórí gbígba béèlì náà.

Ṣáájú ni Adájọ́ Olukayode Adeniyi ti pàṣẹ lọ́jọ́ Kẹjọ, oṣù Kọkànlá ọdún 2023 pé kí wọ́n tú Emefiele sílẹ̀ fún agbẹjọ́rò rẹ̀ lẹ́yìn tó ti lo ọjọ́ 151 ní àhámọ́.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here