Saheed Osupa kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìjìnlẹ̀ ní fásitì Ibadan lẹ́ni ọdún 52

Saheed Osupa kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìjìnlẹ̀ ní fásitì Ibadan lẹ́ni ọdún 52

Fẹ́mi Akínṣọlá

À ṣé òòtọ́ lọ̀rọ̀ àwọn àgbà pé, kò sí ìgbà táà dáṣọ, tá ò rílẹ̀ fi wọ́.Àṣamọ̀ yìí ló jọ ti gbajúgbajà akọrin Fuji, Akorede Babatunde Okunọla tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn mọ̀ sí Saheed Oṣupa bi òun náà ti ṣe wà lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́gboyè ní fásitì Ibadan, UI lọ́jọ́rú.

Saheed Oṣupa kẹ́kọ̀ọ́gboyè ìjìnlẹ̀ ìmọ̀ nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú (Bsc Political Science) ó sì wà lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde Fásitì náà tí wọ́n gbé ọwọ́ oyè lé lórí níbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́gboyè ilé ẹ̀kọ́ náà tó wáyé lọ́gbà Fásitì Ìbàdàn.

Gbajúmọ̀ akọrin náà bọ́ sí ojú òpó sítágíráàmù rẹ̀ láti fọnrere rẹ̀ fún gbogbo àgbáyé pé òun ti di bàbá olóyè tuntun lẹ́ka ètò ẹ̀kọ́.

Saheed Oṣupa tó jẹ́ ẹni ọdún méjìléláàdọ́ta ṣàlàyé nínú àtẹ̀jáde tó fi sí ojú òpó ayélujára rẹ̀ náà pé ìpele òṣùwọ̀n ìjááfá ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Kejì tí òyìnbó ń pè ní Second Class Upper ni òun gbé jáde ní ilé ẹ̀kọ́ náà.

Ọdún 1987 ni Saheed Oṣupa jáde ilé ẹ̀kọ́ girama kí ó tó tẹ̀ síwájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe Polytechnic Ibadan láti gba ìwé ẹ̀rí Ordinary National Diploma nínú ẹ̀kọ́ ìmọ nípa àkóso okoòwò (Business Administration lọ́dun 1992.

Saheed Osupa ń darapọ̀ mọ́ àwọn àgbààgbà òṣèré tí wọ́n ti padà lọ kẹ́kọ̀ọ́gboyè lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí wọ́n ti fi àdàgbá ẹ̀kọ́ tì.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here