Gómìnà tuntun ní Kogi gbàwé ẹ̀rí mo yege
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC ti fún gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ Kogi, Usman Ododo àti igbákejì Joel Salifu ní ìwé ẹ̀rí mo yege.
Ní orúkọ àjọ INEC tó wà ní ìlú Lokoja ni wọ́n ti fi ìwé ẹ̀rí náà lé Ododo àti igbákejì rẹ̀ lọ́wọ́.
Ododo, tí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ní ìbò 446,237 níbi ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ Kọkànlá oṣù Kọkànlá ọdún 2023.
Olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party, SDP, Murtala Ajaka ló tún súnmọ́ Ododo nígbà tí òun ní ìbò 259,052 tí Dino Melaye tẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ní ìbò 46,362 gẹ́gẹ́ bí INEC ṣe kéde.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó gba ìwé ẹ̀rí náà, Ododo ní òun máa ri dájú pé gbogbo ìlérí tí òun ṣe lásìkò ìpolongo ìbò ni òun máa múṣẹ.
Ó ní òun máa gùnlé àwọn àṣeyọrí Gómìnà Yahaya Bello láti mú ìlọsíwájú àti ìṣọ̀kan bá ìpínlẹ̀ Kogi.
Ó tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà fún àtìlẹyìn tí wọ́n ṣe fún òun lásìkò ìbò ní èyí tó ṣàpejúwe gẹ́gẹ́ okùn tó so ìpínlẹ̀ Kogi ró.
Bákan náà ló tún sọ àrídájú rẹ̀ pé ìṣèjọba òun máa mú ìgbélárugẹ àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin ní òkúnkúndùn gẹ́gẹ́ bí ìjọba tó wà lóde náà ṣe ń ṣe.
“Ìpinnu mi láti pèsè iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ àti láti ri pé ètò ẹ̀kọ́ wà ní oókan àyà ìṣèjọba mi kò ní yẹ̀.
“Gbayawu ni ilẹ̀kùn ọ́fíìsì mi máa ṣí fún gbogbo ènìyàn láìfi ẹ̀yà, ẹ̀sìn tàbí ẹgbẹ́ òṣèlú ṣe, gbogbo àwọn ará ìlú ni mà á fún láàyé nínú ìṣèjọba mi.
Gómìnà Yahaya Bello tí òun náà wà níbi ètò náà rọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Edo láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú pẹ̀lú Ododo láti mú ìpínlẹ̀ Kogi gòkè àgbà.
Aṣojú INEC ní ìpínlẹ̀ Kogi, Gabriel Longpet ní ètò náà wà lára ojúṣe INEC lásìkò ìbò.