Má bínú sí mi – Basketmouth rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí AY àti àwọn míràn 

Má bínú sí mi – Basketmouth rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí AY àti àwọn míràn 

 

Mary Fágbohùn

 

Aderinposonu Bright Okpocha, ti a mo si Basketmouth, ti rawo ebe si akegbe re Ayodeji Richard Makun, ti a mo si AY, leyin aawo to wa laarin won fun bii odun metadinlogun.

 

E ranti pe AY ati Basketmouth ti wa ninu iwe irohin lorisirisi nitori aawo to wa laarin won.

 

Irohin jade pe Basketmouth, ni 2021, ninu iforo-wani-lenu-wo ife eye Box pelu atokun eto Ebuka Obi-Uchendu, so pe ija waye laarin oun ati AY nitori pe “o fi jije oloooto mi sere”.

 

“Ni tooto, mi o fe ki okunrin naa (AY) gbo lati odo mi,” ni o so.

 

O fikun un pe won o kii se ore teletele.

 

Nigba ti yoo fesi si aawo olojo pipe naa ninu iforo-wani-lenu-wo pelu atokun eto, Chude Jideon wo ni osu karun-un 2023, AY so pe oro okowo kan to daru ni odun 2006 lo se okunfa aawo naa.

 

Amo sa, Basketmouth, eni to n gbiyanju lati ta iwe iwole sibi ere re to n bo ni osu kokanla, wa aforijin lati odo AY ati awon eniyan miran to se.

 

Nigba to n gba aawo odun metadinlogun ohun, aderinposonu naa, ninu fonran kan to fi lede ni oju awe Instagram re ni ojo Aje, rawo ebe ni gbangba.

 

O wi pe: “Si gbogbo eniyan ni ile ise yi ati omiran ti mo ti se. Mo n so fun n yin bayii lati inu okan mi pe, ki e ma binu si gbogbo nnkan ti mo se, e jowo e darijin mi. Si gbogbo awon ti o fi esun kan mi pe mo se nnkan to pa ise won lara ni ona kan tabi omiran, mi o ni gba tabi ko awon esun yii, sugbon Olorun mo ooto. E jowo e darijin mi.

 

“Si arakunrin mi AY, mi o mo boya irawo ebe mi yoo niyi bayii sugbon ti o ba niyi, jowo darijin mi fun gbogbo nnkan ti mo ti se tabi so seyin to si pa o lara ni onakona. Mo si fe ki o mo pe mo ti dariji o fun gbogbo nnkan ti o se tabi so nigba ti o mo tabi ti o ko mo. O ti lo, mo si fe ki a jo gbe pelu ife ati isokan.

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here