Ìdí tí mo fi yan orin dípò ijó – Asake

Ìdí tí mo fi yan orin dípò ijó – Asake

 

Gbajumo olorin Naijiria, Ahmed Ololade, ti a mo si Asake ti so pe ipinnu oun lati yan orin dipo ijo wa lati ara ife ti oun ni si owo.

 

Asake ninu iforo-wani-lenu-wo kan laipe yi tan imole si oro naa pe oun yan ise orin nitori bi oun se lero pe ijo jijo ko le mu owo ti oun n daniyan wa fun oun.

 

“Idi ti mo fi kuro ninu ijo je nitori ife ti mo ni si owo. Mo fe so ooto. Ijo je nnkan ti mo feran. Sugbon ko da mi loju pe ijo le fun mi ni iru owo ti mo n wa.

 

“Koda bi o ba fe ko da bii ti omo ita ti awon eniyan si n fo lotun ati losi, o nilo lati lo awon onijo. Nitori naa, won n sise papo, mo ro pe nitori ife owo, mo gba ki n di olorin,” ni o so.

 

Nigba ti won bii leere boya yoo yan ijo to ba je pe o fun ni iru aseyori kan naa, olorin naa wi pe: “Rara, maa mu orin ati ijo papo nitori ki n le ni owo to po.”

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here