Àwọn ọmọ Naijiria fẹ́rẹ̀ ba isẹ́ mi jẹ́ nítorí etí ọlọ́pàá tí mo gbá létí – Seun Kuti

Àwọn ọmọ Naijiria fẹ́rẹ̀ ba isẹ́ mi jẹ́ nítorí etí ọlọ́pàá tí mo gbá létí – Seun Kuti

 

Mary Fágbohùn

 

Gbajumo olorin takasufe, Seun Kuti fi esun kan awon omo Naijiria pe wo fere ba ise re leyin gbonmi-sii omi o too pelu oloopa.

 

E ranti pe won gbe Seun lo si ile ejo ipinle Eko ti won si ti mole ni ogba eka to n ri si oro awon odaran ti ipinle (State Criminal Investigation Department, SCID), ni Panti, Yaba, fun esun biba olopaa ja lori afara Third Mainland Bridge ni osu karun-un 2023.

 

Olorin naa ni a ri ninu fonran kan to lo kaakiri lori ayelujara ti o n gba olopaa kan leti leyin ariyanjiyan to jade ti o si di pe o nilo lati gbeja ara re.

 

Nigba to n sasaro lori ohun to la koja ni asiko yi, Seun Kuti ninu eto wo mi ki n wo o kan lori Instagram, wi pe o ku die ki oun padanu gbogbo nnkan ti oun se ninu ise oun nitori isele naa.

 

“O ti su mi bi mo se n ri oruko mi ti won n so po mo Sam Larry, Naira Marley, fifi ofin gbe ati bee bee lo. 

“Bi e se fe fi enu ba aye mi je niyi, o ku die ki e ba ise mi je pelu ero ayelujara yin. Mo padanu ere nla bii marun-un tabi mefa nigba naa lori pe mo fe gbe ara mi ati ebi mi nija. Fun idi eyi awon omo Naijiria fe fi opin si emi mi, fun mi lati di edun arinle ti enikeni ko si bikita nipa re.

 

“Awon kan tile n wo mi bi eni ti ori re ti daru ti o si feran lati maa ru ofin ni gbogbo igba, bee ko si ri bee, eniyan jeje ni mi.

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here