Usman Ododo, àyánrán gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kogi

Usman Ododo, àyánrán gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kogi

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ahmed Usman Ododo tẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ti gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi.

Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC ló kéde yìí lẹ́yìn tí wọ́n ka àkójọpọ̀ àwọn èsì káàkiri ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kànlélógún tó wà ní ìpínlẹ̀ náà.

Gíwà àgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Nsukka, Ọ̀jọ̀gbọ́n Johnson Ozoemenam Urama, tó ń ṣiṣẹ́ fún INEC níbẹ̀ kéde pé Ododo ní ìbò 446,237 láti fẹ̀yìn àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ dupò náà janlẹ̀

Bákan náà ló kéde pé olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, Dino Melaye rí ìbò 46,362 tí Murtala Ajaka, ti ẹgbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party, SDP ní ìbò 259,052.

Ododo gbégbá orókè ní ìjọba ìbílẹ̀ ….. nígbà tí Melaye gbégbá orókè ní ìjọba ìbílẹ̀ …. tí Ajaka náà sì jáwé olúborí ní ìjọba ìbílẹ̀ …..

Ní ọjọ Kọkànlá, oṣù Kọkànlá ọdún 2023 ni ètò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi wáyé tí INEC sì kéde ṣíṣe ìdádúró ìbò dídì ní wọ́ọ̀dùn mẹ́sàn-án látàrí àwọn kùdìẹ̀kudiẹ kan tó wáyé ní àwọn ibùdó ìdìbò náà.

Nǹkan bí aago mẹ́wàá òwúrọ̀ kọjá ní ọjọ́ Àìkú ni ètò kíkéde èsì ìbò bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Lokoja tó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Kogi.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here