Mo lè jí Mohbad dìde – Wòólì béèrè fún òkú olórin náà

Mo lè jí Mohbad dìde – Wòólì béèrè fún òkú olórin náà

 

Mary Fágbohùn

 

Wooli kan to pe ara re ni Oba Ewulomi ti so pe oun le ji oku olorin Naijiria Ilerioluwa Aloba, ti a mo si Mohbad dide.

 

E ranti pe Mohbad jade laye ni ona to sokunkun ni ojo kejila osu kesan-an odun 2023, ti won si sin in  ni ojo keji.

 

Ara re ni won pada wu jade fun ayewo oku leyin ti opolopo n beere fun iwadii lori ohun to se okunfa iku ojiji naa.

 

Oku naa ni won gbe lo si ile igbokupamo leyin ti won se ayewo oku tan, gege bi ohun ti awon olopaa so.

 

Ni bayii, Wooli Ewulomi beere fun anfaani lati de ibi ti oku olorin naa wa, o si seleri lati ji dide.

 

Nigba to n soro pelu apapo ede Geesi ati Yoruba ninu fonran kan to ti n lo kaakiri lori X, wooli naa tenumoo pe “Mohbad si le wa laye leekan sii.”

 

O wi pe, “Mo seleri pe Imole Mohbad si le wa laye leekan sii. E fun mi ni anfaani lati ri oku re,  maa si ji dide. Bee ni.”

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here