Ìdìbò Gómìnà Bayelsa: Òjò owó dunlẹ̀ fáwọn oní kátàkárà ìbò

Ìdìbò Gómìnà Bayelsa: Òjò owó dunlẹ̀ fáwọn oní kátàkárà ìbò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò jọ pé ìṣẹ́ òhun òṣì tó
mu àwùjọ dúndúndún le jẹ́ kí òpin dé bá àṣà dìbò kóo sebẹ̀ tó gbajúgbajà láwọn ibùdó ìdìbò wa èyí tó má a n wáyé láwọn àkókò ìbò.
À fi ìgbà tí eji ń pitú, bẹ́ẹ̀ lòjò owó ń rọ̀ ní ìpínlẹ̀ Bayelsa, lásìkò ètò ìdìbò sípò Gómìnà tó wáyé níbẹ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kọkànlá, oṣù Kọkànlá, ọdún yìí, pẹ̀lú báwọn olùdíje ṣe ń fowó táákà láti ra ìbó àwọn olùdìbò, táwọn olùdìbò náà sì ń ṣe kùkùkẹ̀kẹ̀ láti pawó sápò kóówá wọn.

Níbi tọ́rọ̀ ọ̀hún le dé , báwọn ẹ̀ṣọ aláàbò bíi ọlọ́pàá àtàwọn sífú dìfẹ́nsì, títí kan àwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó ń gbógun ti jìbìtì lílù àti ṣíṣe owó ìlú mọ́kumọ̀ku, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), àti ti Independent Corrupt Practices and Related Offenses Commission (ICPC), ṣe dúró wámúwámú kò dí àwọn ràbòràbò ọ̀hún lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ lawọn olùdìbò kò jafara láti gba owó sápò pẹ̀lú.

Ohun táa gbọ́ ni pé láwọn ibùdó ìdìbò kan, níṣe làwọn àgbàlagbà méjì kan ń darí àwọn olùdìbò tó ń dé láti dìbò sí ọ̀dọ̀ obìnrin kan tó gbé àga sí ibik kọ̣́lọ́fín kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà síbùdó ìdìbò ọ̀hún, obìnrin yìí ló ń sanwó fún wọn láti fi ra ìbò wọn, pẹ̀lú àdéhùn ẹgbẹ́ tí wọn yóò dìbò fún.

Wọ́n ní báwọn olùdìbò yìí bá ti dìbò tán ni won yóó tùn ṣẹ́rí sọ́dọ̀ obìnrin yìí, láti gba owó lẹ́ẹ̀kejì, ìyẹn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fi ẹ̀rí àrídájú hàn pé àwọn ti dìbò náà gẹ́gẹ́ bíi àdéhùn wọn ìṣaájú

Akọ̀ròyìn ìwéèròyìn The Nation, sọ pé àwọn agbófinró ni wọ́n ń tọ́ka kọ̀rọ̀ ibi táwọn tó ń ra ìbó jókòó sí, tí wọ́n sì ń ṣe atọna àwọn olùdìbò láti lọ gbowó, bẹ́ẹ̀ lawọn olùdìbò kan ń fi ìwé ìdìbò wọn han àwọn oníròyìn tí wọ́n wà lórí ìdúró, wọ́n rò pé lára àwọn ràbóràbò tó máa fún wọn lówó ni wọn.

Àmọ́ wọ́n láwọn olùdìbò kan kò fi ìwé ìdìbò wọn sínú àpótí lẹ́yìn ìdìbò, níṣe ni wọ́n mú un lọ fáwọn tó ń ra ìbò, tí wọ́n sì ń gbowó sápò.

Ìwádìí fihàn pé àwọn olùdìbò kan gba ẹgbẹ̀rún mẹ́ta Náírà, àwọn kan gba ẹgbẹ̀rún márùn-ún Náírà láwọn ibòmí-ìn, nígbà tí wọ́n san ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá Náírà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ fáwọn mí-ìn.

Ní ìpínlẹ̀ Kogi, bákan náà lọrọ ṣe rí láwọn ibùdó ìdìbò kan, pàápàá lágbègbè Lokoja, tí í ṣe olú-ìlú ìpínlẹ̀ ọ̀hún, àwọn èèyàn ń gbowó kí wọ́n tóó dìbò, tí wọ́n sì tún ń gbowó lẹyìn tí wọ́n bá dìbò tán.

Àwọn éjẹ́ntì ẹgbẹ́ òṣèlú wà lọ́ọ̀ọ́kán tí kò jìnnà sáwọn olùdìbò yìí, ibẹ̀ ni wọ́n ti ń há owó fáwọn olùdìbò, tí wọ́n sì ń pàrọwà sí wọn láti dìbò fún ẹgbẹ́ òṣèlú kóówá wọn.

Lára nnkan tí wọ́n kọ́kọ́ ń bèèrè kí wọ́n tóó sanwó ni káàdì ìdìbò alálòpẹ. Wọ́n ní níṣe làwọn éjẹ́ntì náà ń lọ káàkiri láti ibùdó ìdìbò kan sí òmí-ìn láti rí i pé àwọn fowó wá àtìlẹ́yìn olùdìbò púpọ̀ fún ẹgbẹ́ wọn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here