Mo rè pé ẹ̀gbọ́n mi Niniola ń jowú mi – Teni

Mo rè pé ẹ̀gbọ́n mi Niniola ń jowú mi – Teni

 

Gbajumo olorin, Teniola Apata, ti a mo si Teni, ti safihan pe oun figba kan ro pe egbon oun obinrin, olorin Niniola, n jowu ebun ti oun ni nitori bi o se n da ohun ti oun fi n korin lejo.

 

Nigba to n seranti oro ninu ijiroro kan pelu Tea With Tay podcast, Teni ranti pe oun n se igbaradi orin pelu awon arabinrin oun nigba ti won wa ni kekere.

 

O ni egbon awon agba, Doyin so pe oun ni ohun to dun, sugbon Niniola so pe ohun ko “dun”.

 

O ni oro ti o so naa mu ki oun ro pe o n jowu oun.

 

Teni wi pe, “Egbon mi, eyi to ju Nini [Niniola] lo, Doyin, boya o n tan mi nitori pe ko fe bami ninu je; maa n so fun mi pe mo ni ohun to dun nigbakugba ti mo ba korin nigba kekere mi. Nini, ni ona keji, yoo so pe ohun mi ko dun. Nitori naa, mo ro pe o n jowu mi.

 

“O [Niniola] pe mi si egbe kan wi pe ki n ma se je ki Doyin tan mi. O wa so pe, ‘Waa korin lati inu re.’ Nitori naa, nigbakugba ti Nini ba korin, maa wo bi o se n korin. Nitori naa, emi naa bere si ni korin lati inu mi.

 

“Igba kan wa ti ile iwe mi sagbekale ayeye kan, mo korin, gbogbo ile iwe si dide lati patewo fun mi. Mo so pe, ‘Mo ti de.’ Mo lo sile lo so fun Nini pe mo korin ni ile iwe ati pe gbogbo eniyan si patewo fun mi, leyin naa, o so fun mi pe ki n ko orin ti mo ko. Mo ko orin naa Nini pelu si patewo fun mi. Mo so pe, ‘O dara, a n ba nnkan bo.’”

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here