Èèmọ̀, Pásítọ̀ Ṣẹgun ríran èké s’ọ́mọ ìjọ rẹ̀, ló bá fi ọgbọ́n bá a sùn kárakára
Fẹ́mi Akínṣọlá
Kò séèyàn mọ́ ni ariwo tí àwọn èèyàn tó gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àgbọ́ṣehà kan, níbi tí pásítọ̀ ìjọ Kérúbù àti Séráfù, ‘Cherubim And Seraphim’ tó wà lágbègbè Agbado, níìpínlẹ̀ Ogun, Ọ̀gbẹ́ni Sunday, ti ríran èkè sí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀, Omidan Aliu Blessing, ẹni ọdún mọ́kànlélógún, tó sì fipá bá a sùn láìmọye ìgbà níbi tó jí i gbé pamọ́ sí.
Ohun tí a gbọ́ ni pé nítorí pé ara ọ̀kan lára àwọn àbúrò ọmọbìnrin náà tí kò yá ló gbé e dé ṣọ́ọ̀ṣí Pásítọ̀ Ṣẹgun yìí lọ́jọ́ kejì, oṣù kejì, ọdún 2023 yìí, pẹ̀lú ìrètí pé àbúrò rẹ̀ yìí yóó rí ìwòsàn gbà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n èyí tí ọkùnrin tó pera rẹ̀ ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí ì bá fi tán òkè ìṣòro tí Blessing gbé lọ síwájú rẹ̀, níṣe ló tún dá kún un pẹ̀lú ìran èké tí pásítọ̀ ọ̀hún rí sí i. Ó sọ fún un pé èmí Ọlọ́run sọ fóun pé ó máa kú lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀ gan-an, bí kò bá gbà láti lájọṣepọ̀ ìkọ̀kọ̀ pẹ̀lú òun. Ó tún sọ fún un pé bí ọkùnrin mìíràn bá gbìyànjú láti bá a lájọṣepọ̀ yàtọ̀ sí òun, onítọ̀hún máa kú . Ìbẹ̀rù gbogbo ohun tí pásítọ̀ yìí sọ ló mú kí ọmọbìnrin náà gbà fún un, ló bá ń bá a lò pọ̀ bó ṣe wù ú.
Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún múlẹ̀ ní olú-iléeṣẹ́ wọn tó wà ní Eleweeran, nílùú Abẹokuta, Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn, S.P Ọmọtọla Odutọla, sọ pé, ‘‘Lóòótọ́, ọ̀dọ̀ wa ni pásítọ̀ Ṣẹgun wà, a ti bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ti jẹ́wọ́ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Omidan Blessing lákàtà rẹ fún wa pátá. Nǹkan bíi oṣù méje ni ọmọbìnrin yìí fi wà lọ́dọ̀ rẹ̀, níbi tó jí i gbé pamọ́ sí. Fún gbogbo àkókò tí pásítọ̀ ọ̀hún fi jí Blessing gbé pamọ́ làwọn ẹbí rẹ̀ fi ń wá a káàkiri. ‘‘Ọgbẹni Aliu Yusuff tí i ṣe ẹgbọn Blessing lo lọọ fiṣẹlẹ náà tó àwọn ọlọ́pàá agbègbè wọn létí lẹ́yìn tí àbúrò rẹ̀ padà wá sílé. Ó ní ẹnu ya gbogbo àwọn nígbà táwọn tún fojú kàn án lọ́jọ́ Karùn-ún, oṣù Kọkànlá, ọdún yìí.
‘‘Ẹ̀gbọ́n Blessing ní àbúrò òun sọ fáwọn pé gbàrà táwọn kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì Pásítọ̀ Ṣẹgun ló ti lọ fi òun han àwọn ẹbí rẹ̀ kan nílùú Ilaro, tó sì tún lọ gba òtẹ́ẹ̀lì fóun, látìgbà náà ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá òun lájọṣepọ̀ pẹ̀lú ipá nígbà gbogbo, àti nígbàkúùgbà tó bá wùú ’’.
Alukoro ní gbogbo báwọn ṣe ń bi pasitọ náà léèrè ọ̀rọ̀ ló ń bá àwọn sọ̀rọ̀, kò sì fi ẹyọ kan pe méjì fáwọn rárá. Ó ní ọkùnrin náà máa tó fojú balé ẹjọ́.