Ààfáà kẹ̀! Wọ́n tún ká orí àti ọwọ́ èèyàn tútù mọ́ Ààfáà Hasaan lọ́wọ́ n’Íbàdàn

Ààfáà kẹ̀! Wọ́n tún ká orí àti ọwọ́ èèyàn tútù mọ́ Ààfáà Hasaan lọ́wọ́ n’Íbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ègbìrìn ọ̀tẹ̀,bí wọ́n ṣe n paná ọ̀kan bẹ́ẹ̀ lòmíràn n rú túú bí iná ẹ̀ẹ̀rùn.
Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ àwọn ààfáà mẹ́ta kan fún bí wọ́n ṣe gé orí àtàwọn ẹ̀yà ara èèyàn n’Íbàdàn, tí wọ́n sì ti wà láhàámọ́ ọgbà ẹ̀wọn báyìí, ọwọ́ tún ti tẹ ààfáà mí-ìn tí wọ́n tún ká orí àti apá èèyàn mọ́ lọ́wọ́.

Afurasí ọ̀daràn ọ̀hún, Hassan Kọlawọle, tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínláàádọ́ta (45) lọwọ́ àwọn agbófinró tẹ̀ níbi tó ti ń gbìyànjú láti fi orí àti apá èèyàn méjì jóògùn.

Orí pẹ̀lú apá èèyàn méjèèjì ọ̀hún ló jẹ́ ti ẹnìkan tá ò tí ì mọ, tá ò sì mọ irú ikú tó pa á títí a fi parí àkójọ ìròyìn yìí.

Lọjọ Ẹtì, ọjọ́ kẹwàá, oṣù Kọkànlá, ọdún 2023 yìí, ni Alukoro ileeṣẹ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́,

SP Adewale Ọṣifẹṣọ, ṣàfihàn ọkùnrin náà fáwọn oníròyìn tóun ti orí àti apá méjèèjì tí wọ́n ká mọ ọn lọwọ́.

SP Ọṣifẹṣọ, ẹni tó ṣèpàdé oníròyìn ọ̀hún lórúkọ CP Adebọla Hamzat, ti í ṣe ọgá àgbà àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ṣàlàyé pe “awọn eeyan ti ọrọ ètò ààbò ìlú jẹ lógún ni wọn ta wa lolobo pe àwọn oniṣẹ ibi kan máa ń fi ẹyà ara èèyàn ṣòògùn ládùúgbò Ogbere-ti-o-ya, n’Ibadan.

“ Ìyẹn làwọn ọlọ́pàá teṣan Iyaganku, n’Ibadan, ṣe sare lọ sibẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣù yìí, tí wọ́n fi mú afurasí ọdaràn yìí tó ń jẹ́ Hassan Kọlawọle, ko too di pe o fi awọn ẹya ara naa ṣe ohunkohun.

“ Afurasí ọ̀daràn yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tó ń fi ẹ̀yà ara èèyàn ṣòògùn owó, ṣùgbọ́n tí wọ́n kàn ń fi iṣẹ́ ààfáà bójú láti tan àwọn èèyàn jẹ”.

Nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè àwọn oníròyìn lólú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó wà ládùúgbò Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, afurasí ọkùnrin tó pera ẹ̀ láàfáà yìí fìdí ẹ múlẹ̀ pé òun lòun ni orí àtàwọn ọwọ́ èèyàn ọhún lóòótọ́, ṣùgbọ́n òun kọ lòun pa ẹni náà, ẹnìkan tó ń jẹ́ Tijani Waheed, lo gbé àwọn kinní náà wá fún òun.

Ó ṣàlàyé pé níbi ayẹyẹ ìrántí ọjọ́ọ̀bí Ànábì ti wọ́n ń pè ní Maloud lóun ti pàdé Waheed, níbi tí àwọn ti ń sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe rí ní Nàìjíríà lọkùurin náà sọ fóun pé òun ní òògùn àṣírí owó kan tó lágbára lọ́wọ́, ṣùgbọ́n aájò ọ̀hún jẹ mọ́ orí àti ọwọ́ èèyàn méjèèjì.

Ó ní nígbàtí òún sọ fún un pé òun kò mọ ibi tí òun ti lè rí i ló fi òun lọ́kàn balẹ̀ pé kí òun má ṣe fòyà, ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lòun sì pè é lọ́jọ́ náà lọ́hù-ún, àfìgbà tó gbé àwọn ẹ̀yà ara èèyàn tútù náà wá fóun lóòótọ́.

Ìwádìí àwọn agbófinró ṣì ń tẹ̀síwájú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí SP Ọṣifẹṣọ tíí ṣe agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here