Babaláwo àtàwọn mẹ́rin mí-ìn wẹ̀wọ̀n, aṣòfin kan ni wọ́n lù ní jìbìtì

Babaláwo àtàwọn mẹ́rin mí-ìn wẹ̀wọ̀n, aṣòfin kan ni wọ́n lù ní jìbìtì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí irọ́ bá lọ lógún ọdún, ọjọ́ kan péré lòótọ́ yóó le bá.
Adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ kan tó wà nílùú Oṣogbo, ti dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún fún babaláwo kan àtàwọn mẹ́rin mìíràn tí wọ́n lu olórí iléègbìmọ̀ aṣòfin Ọ̀ṣun àná, Ọnarébù Timothy Owoẹyẹ, ní jìbìtì owó ńlá.

Mílíọ̀nù méjìdínlógójì Náírà ni wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn èèyàn ọ̀hún pé wọ́n gbà lọwọ́ Owoẹyẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tún fi fọto ìhòòhò rẹ̀ sórí ìkànnì ayélujára láti lè fi dúnkookò mọ́ ọn, kí wọ́n lè rí owó gbà sí i lọ́wọ́ rẹ̀.

Ọdún 2018 làwọn ọlọ́pàá fi páńpẹ òfin gbé Kazeem Agbabiaka, Fẹmi Oyebọde, Abdul-Rasheed Ọjọnla, Babatunde Oluajọ, Adebiyi Kehinde, Oyebanji Oyeniyi àti Ismaila Azeez lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àwọn méjèèje kọ́kọ́ fara hàn nílé-ẹjọ́ májísíréètì kó tóó di pé wọ́n taari ẹjọ́ wọn sílé-ẹjọ́ gíga tìjọba àpapọ̀ lóṣù Kẹwàá, ọdún 2018.

Lára ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n ni ìgbìmọ̀-pọ̀ láti hùwà búburú, lílu jibiti lórí ẹ̀rọ ayélujára, fífi ìkànnì ayélujára dunkookò mọ́ èèyàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Lásìkò ìgbẹ́jọ́ yìí, igbákejì dàrẹ́kítọ̀ tó ń gbọ́ ẹjọ́ aráàlú, Bàrísítà Moses Faremi, kó ẹ̀rí mẹ́tàdínlọ́gọ́ta kalẹ̀, lára rẹ̀ ni ìwé àkọsílẹ̀ báńkì, àpótí onígi kan, owó dọ́là ọgọ́rùn-ún kan, ìbọn àtàwọn nǹkan míràn.

Bákan náà ló pe ẹlẹrìí mẹ́fà, nínú èyí tí olupẹjọ fúnra rẹ̀ wà, ó pé ọlọpaa tó ń ṣèwádìí ẹsùn náà àtàwọn òṣìṣẹ́ báńkì mẹ́rin láti jẹ́rìí ta ko àwọn olùjẹ́jọ́.

Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ keje, oṣù Kọkànlá, ọdún yìí, Onídàájọ́ Emmanuel Ayọọla, sọ pé àwọn márùn-ún lára àwọn olùjẹ́jọ́ jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Ó ní Agbabiaka tó jẹ́ babaláwo, Oyẹbọde tó jẹ́ aṣáájú kan nínú ìlú náà, Babatunde tóun jẹ́ ọmọọba àti Kehinde jẹ̀bi ẹ̀sùn ìgbìmọ̀-pọ̀ hùwà búburú àti lílu jìbìtì lórí ẹ̀rọ ayélujára, nígbà tí Adebiyi jẹ̀bi fífi ìkànnì ayélujára dúnkookò mọ́ èèyàn.

Onídàájọ́ Ayọọla yọ orúkọ Abdul-Rasheed Ọjọnla kúrò lára wọn nítorí pé ó ti sá lọ lásìkò ìgbẹ́jọ́, ó sì sọ pé kí Azeez máa lọ lálàáfíà nítorí kò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.

Ó ni olùjẹ́jọ́ ti fi ìdí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn àwọn olùjẹ́jọ́ náà múlẹ̀ kọjá iyèméjì, ó sì hàn gbangba pé wọ́n lu Owoẹyẹ ní jìbìtì mílíọ̀nù méjìdínlógójì Náírà, bẹ́ẹ̀ ni wọn tún ba orúkọ rẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ fífi fọ́tò ìhòòhò rẹ̀ síta.

Nítorí náà, ó ní kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lọ fi ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún jura.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here