Èmi kọ̀ ló pa ọkọ mí, Wumi, aya Mohbad fọhùn

Èmi kọ̀ ló pa ọkọ mí, Wumi, aya Mohbad fọhùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí ọ̀rọ̀ nlá kò bá tíì tán, èèyàn nlá kò ní-ín sinmi àròyé.
Ó tó wákàtí mẹ́ta tí Ìyàwó Mohbad, Wunmi Alọba, fi ṣàlàyé ohun tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tó fa ikú ọkọ rẹ̀, Ileri Oluwa Alọba táwọn èèyàn mọ̀ sí Mohbad, ìyẹn níbi tí wọ́n ti ń gbọ́ ẹjọ́ ìwádìí ikú olóògbé ọ̀hún ní ìpínlẹ̀ Èkó, lọ́jọ́ Ìṣẹgun ọ̀sẹ̀ yìí.

Ọkọ mi àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ jà n’Ikorodu lóòótọ́, ó fi ara pa, ara rẹ̀ kò balẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tí nọ́ọ̀sì fún un lábẹ́rẹ́, ikú ni mo gbọ́ lẹ́yìn ìyẹn

Wunmi ṣàlàyé pé ìjà kan wáyé láàrin ọkọ òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀, Prime Boy, lẹ́yìn tí Mohbad parí eré n’Ikorodu lálẹ́ ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹsàn-án, táwọn fẹ́ máa lọ sílé ṣùgbọ́n tí àwọn olólùfẹ rẹ̀ kò jẹ́ kí àwọn rí ọ̀nà gbà.

Ó ní àbúrò Mohbad, Adura Alọba, tó fẹ́ lọ pé àwọn tí yóó le àwọn èrò tó wà lọ́nà kúrò pẹ́ kó tó dé, èyí sì dohun tí Prime Boy bínú sí àbúrò Mohbad tíyẹn náà sì dá a lóhùn padà.

Ọ̀rọ̀ náà ló ní ó di ìjà láàrin Mohbad àti Prime Boy, ti Olóògbé fi ṣílẹ̀kùn mọ́tò rẹ̀ tó sì ní kí Prime Boy sọ̀kalẹ̀.

Wumi sọ pé òun kò mọ ohun tó padà ṣẹlẹ̀ mọ́ nítorí òun ti kúrò níbẹ̀ láti pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá dá sí i, nígbà tóun dé, lòun rí i pé Mohbad ti fi ọwọ́ ṣèṣẹ

Ó fi kún un pé Mohbad kò lọ sọ́sibítù bóun ṣe gbà á nímọ̀ràn lọ́jọ́ kejì tó fi ọwọ́ ṣèṣe níbi ìjà náà, òun ń bá a fi nǹkan pa á ni.

Ọ̀rẹ́ rẹ̀, Spending, to ń gbé pẹlú àwọn ló sì bá a pe nọ́ọ̀sì tó fún un lábẹrẹ́ náà.

Nítorí nọ́ọ̀sì tó máa ń tọ́jú Mohbad kò sí nítòsí

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here