Olórí ilé aṣòfin Òǹdó ké gbàjarè,pé wọ́n ń lépa ẹ̀mí òun

Olórí ilé aṣòfin Òǹdó ké gbàjarè,pé wọ́n ń lépa ẹ̀mí òun

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní a kìí dákẹ́ ẹ́ kú.Ó jọ pé ọ̀rọ̀ awuyewuye lórí ìyọninípò igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó tún ti gba ọ̀nà mìíràn yọ pẹlú bí Olórí ilé aṣòfin Òǹdó ṣe ké gbàjare pe káwọn agbófinró ṣàájú òun torí ìdúnkokò ẹ̀mí.
.
Olamide Oladiji tó jẹ́ olórí ilé sọ pé àti òun àti àwọn ọmọ ilé ní ọkàn àwọn ò balẹ̀ mọ́ láti ìgbà tí àwọn bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ láti yọ igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Lucky Aiyedatiwa kúrò nípò.

Lásìkò tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní Àkúrẹ́ ló ke gbàjarè yìí lọ́jọ́ Ajé.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wí , ó ní ”lówùúrọ̀ yìí ni mo tún bá ẹbọ táwọn èèyàn kan gbé sí iwájú ilé ìgbé ti ìjọba là kalẹ̀ fún mi”

Ó ní ilé ìgbé yi tó nílò àtúnṣe jẹ́ ibi tóun kò sábà máa lò sí.

Ó ní ìpàdé ẹ̀ẹ̀kànkan àwọn ọmọ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ làwọn máa ń ṣe níbẹ̀.

”Lówùúrọ́ yí ni mo rí ẹbọ tí èèyàn kan gbé sí iwájú ilé yìí. Yàtọ̀ sí eléyìí mo ti ń gba ìpè lórí ago táwọn kan fi ń dúnkookò mọ́ ẹ̀mí mi àti àwọn ọmọ ilé aṣòfin mí-ìn.Ìdààmú yí pọ̀ lórí ẹ̀mí mi”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here