Ó gbọdọ̀ tọrọ àforíjìn – Afẹ́nifẹ́re sí Ọbásanjọ́

Ó gbọdọ̀ tọrọ àforíjìn – Afẹ́nifẹ́re sí Ọbásanjọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní tẹni n tẹni àkísà ni tààtàn ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re ilẹ̀ Yorùbá ti korò ojú sí Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí, Olóyè olusegun Obasanjo lórí ìhùwàsí rẹ̀ s’áwọn Orí-adé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Fídíò tó ṣàfihàn bí Obasanjo ṣe peṣẹ́ fáwọn ọba alayé náà pé kí wọ́n dìde kí wọ́n sì tún jókòó lásìkò tí Gómìnà Seyi Makinde dé sí ibi ètò tí wọ́n wà di iṣu ata yán-an yàn-an pàápàá jùlọ lórí ayélujára.

Nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lẹ́yìn ìpàdé rẹ̀ ní Ọjọ́rú nílùú Àkúrẹ́, Afẹ́nifẹ́re sọ pé Obasanjo gbọdọ̀ tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ àwọn Orí-adé tọrọ kàn.

Afẹ́nifẹ́re sọ nínú àtẹ̀jáde tí akọ̀wé ẹgbẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Jare Àjàyí kà síta pe “ìyàlẹ́nu ní ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹ̀sán án nílùú Iṣẹyin jẹ́ níbi tí Obasanjo ti pàṣẹ fáwọn ọba alayé tó sì tún sọ fún wọn pé kí wọ́n jókòó padà.

Níṣe ló dàbí ẹni pé ọ̀gágun kan ló ń peṣẹ́ fáwọn ọmọ ogún.

Àwa Yorùbá bọ̀wọ̀ fún àṣà wa àtàwọn tó jẹ́ aṣojú àṣà wa bákan náà eléyìí tí í ṣe àwọn ọba alayé.

Àti wípé kìí ṣe lásán ni Yorùbá máa ń pe àwọn ọba ní igbákejì òrìṣà.

Ìdí èyí ni àwa ẹgbẹ́ Afenifere fi képe Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ láti tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ àwọn ọba alayé yìí.

A kò gbọdọ̀ fààyè gba ẹnikẹ́ni láti tàbùkù àṣà àti ìṣe wa nílẹ̀ Yorùbá.

Èyí gan an làwọn Ọba kò ṣe máa dìde láwùjọ láti kí ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti káàkiri àgbáyé.”

Ẹ̀wẹ̀, Afenifere tún képe ìjọba àpapọ̀ lórí ètò àbò tó mẹ́hẹ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ẹgbẹ́ náà ní ìjọba gbọdọ̀ ri pé ètò àbò múlẹ̀, àti pé ìjọba gbọdọ̀ wá iṣẹ́ fáwọn ọ̀dọ̀ torí ọwọ́ tó bá dilẹ̀ ni Èṣù máa ń bẹ́ níṣẹ́ k’íṣẹ́.

Afenifere ní ìjọba gbọdọ̀ ri pé àwọn agbésùnmọ̀mí, jàǹdùkú àtàwọn tó ń tì wọ́n lẹ́yìn gbọdọ̀ fojú winá òfin.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here