Ẹ kó ìbọn yín lọ síléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún àtùngbéyẹ̀wò –Ọ̀gá ọlọ́pàá

Ẹ kó ìbọn yín lọ síléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún àtùngbéyẹ̀wò –Ọ̀gá ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọn ní tojútìyẹ́ ni àparò fi í ríran.Kómi ó má ba à wá tẹ̀yìn wọ̀gbín lẹ́nu látàrí bí àwọn ẹrúukú ṣe ń kó oríṣìíríṣìí ìbọn àtàwọn ohun ìjà olóró pamọ́ sílé, ọgá àgbà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, CP Adebọla Hamzat, ti kìlọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà láti tètè lọ jọ̀wọ́ àwọn nǹkan ìjà olóró náà sílẹ̀ fáwọn agbófinró tàbí kí òun tẹsẹ̀ bọ ṣòkòtò kan náà pẹ̀lú wọn.

Nígbà tí Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ń lu aago ìkìlọ̀ náà ṣétí àwọn tọ́rọ̀ ọ̀hún kan lórúkọ ọgá àgbà ọlọ́pàá, ló ti sọ pé ọ̀rọ̀ yìí kò yọ àwọn tó ní ìwé àṣẹ fún ìbọn wọn sílẹ̀.

Ìyẹn ni pé bí àwọn tó ń lo ìbọn lọ́nà àìbófin mu gbọdọ̀ ṣe jọ̀wó ẹ̀ sílẹ̀, káwọn tó ń lò ó lọ́nà tó bófin mu náà fi tiwọn pàápàá sílẹ̀ fún àyẹ̀wò àti àtúnṣe ìwé àṣẹ wọn.

Oṣifẹsọ ní èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin ọdún 2004, èyí

tó de àwọn ohun ìjà olóró, ìdí nìyẹn tí òun fi rọ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí irú ohun ìjà báyìí bá wà níkàáwọ́ wọn láti kó wọn lọ sí téṣàn ọlọ́pàá tó bá wà nítòsí wọn, àti pé ìgbésẹ̀ náà kò ná wọn lówó kankan.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, “Ìkéde tí CP Hamzat ṣe yìí wáyé lẹ́yìn tí Ọgá àgbà ọlọ́pàá lórílẹ̀-èdè yìí, AIGP Kayọde Ẹgbẹtokun, pàṣẹ pé kí àwọn ọlọ́pàá káàkiri ìpínlẹ̀ gbogbo lórílẹ̀-èdè yìí wá gbogbo ọ̀nà láti paná ìwà ọ̀daràn nílẹ̀ yìí, èyí tó ń wáyé látàrí bí àwọn nǹkan ìjà olóró ṣe pọ̀ láwùjọ.

Àtẹ̀jáde ọ̀hún ṣàlàyé pé èyí kò yọ àwọn tó láṣẹ láti ní irú àwọn ohun ìjà yìí lọ́wọ́, kí wọ́n baà lè ṣàtúngbéyẹ̀wò lánsẹ́nsì wọn.

Ó wáá rọ àwọn aráàlú tó bá ní ohunkóhun tí wọ́n fẹ́ ẹ́ fi tó àwọn agbófinró létí láti pe ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá sórí àwọn nọ́mbà wọ̀nyí:0705549513 àti 08081768614 pẹ̀lú nọ́mbà ètò ààbò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ìyẹn 615.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here