Ojú ù mi rí hèèmọ̀ níléeṣẹ́ Bayowa, mo ta dúkìá san gbèsè– Busola Oke Eleyele

Ojú ù mi rí hèèmọ̀ níléeṣẹ́ Bayowa, mo ta dúkìá san gbèsè– Busola Oke Eleyele

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé yorùbá bọ̀ wọ́n ní ìrírí làgbà. Bẹ́ẹ̀, ó níbi tí èèyàn bá ọ̀rọ̀ dé, kó tó kan ìbéèrè pé, ṣé ó ṣe ọ́ rí?
Ìràwọ̀ olórin ẹ̀mí, Busola Oke tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ẹlẹ́yẹlé ti fẹnu yẹpẹrẹ alágbàtà fíìmù àti orin nígbà kan, Gbenga Adewusi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bayowa Films and Record International.

Busola Oke nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn tó máa ń gbé àwọn olórin lárugẹ ṣe máa ń lò wọ́n láti fi pa owó sí àpò ara wọn láì fún àwọn olórin náà ní àǹfàní láti jẹ èrè iṣẹ́ wọn.

Nínú fídíò kan tí Busola Oke tó ṣe lórí TikTok rẹ̀ ní ojú òun rí tó lọ́wọ́ Bayowa nítorí òun kò rí àǹfàní kankan jẹ lórí àwọn orin tí òun ṣe lábẹ́ ilé iṣẹ́ rẹ̀.

Ó ní òun ta ilé àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá òun nítorí òun kò ì tíì bọ́ lọ́wọ́ àkóbá tí Bayowa ṣe fún òun nígbà tí òun wà lábẹ́ rẹ̀.

Ó gba àwọn olórin tó bá ń dìde lásìkò yìí láti la ojú wọn sílẹ̀ dáradára kí wọ́n má ba à kósí ọwọ́ àwọn tí wọ́n máa ba ògo wọn jẹ́.

Ó kọminú pé òun kò rí ẹnìkankan ta òun lólobó nígbà tí òun fẹ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Bayowa pé oore ẹ̀dẹ ni òun fẹ́ gbà pé òun kò bá má ti torí bọ̀ ọ́ tàbí kó sí abẹ́ rẹ̀.

Busola Oke ṣàlàyé pé lẹ́yìn tí àwọn ṣe orin ìkẹyìn fún olóògbé Gbenga Adeboye ni Bayowa pe òun pé kí òun wá ṣe orin fún iléeṣẹ́ òun.

Ó tẹ̀síwájú pé ìgbà náà ni òun ṣàlàyé fún pé òun ní orin kan tí òun ń ṣe lọ́wọ́ tó sì ní kí òun wá àwọn orin mìíràn mọ́ tí òun sì ṣe bẹ́ẹ̀.

“Tí wọ́n bá sọ wí pé àwọn nǹkan báyìí ni mo ti kójọ nílé ayé mi níbi tí àwọn àwo orin tí mo ṣe fún Bayowa tà dé, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

“Nǹkan tí àwọn promoter máa ;ń ṣe ni pé wọ́n máa ń sọ ènìyàn di ẹrú títí ayérayé, tí ènìyàn yóò máa sìn wọ́n títí tó máa fi kú.”

“Nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàárín èmi àti Bayowa nìyí, ó fẹ́ sọ mí di ẹrú ayérayé ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ wà lọ́wọ́ Ọlọ́run.”

Bákan náà ló kọminú pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni ó yẹ kí òun ti gbéṣe ṣùgbọ́n tí òun kò lè ṣe tí àwọn kan sì ń fi òógùn òun jẹ ayé.

Ó ní òun gbà pé Ọlọ́run nìkan ló máa dájọ́ láàárín òun àti Bayowa fún gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here