A wọ́gilé oyè yówù tí ọ̀ba yorùbá fi Obasanjo jẹ – YCW

A wọ́gilé oyè yówù tí ọ̀ba yorùbá fi Obasanjo jẹ – YCW

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní bí a ò bá yọ ipin ká fi han ojú, ó ṣeéṣé kí ojú má mọ̀ pé òhun ń ṣe ọ̀bùn, àti pé bí a bá ṣòògùn ẹ̀tẹ̀,ọmọọ̀yá ẹni la fi í dánwò,kí ọmọ baba lè rí ni sá tèfètèfè.
Ẹgbẹ́ ọmọ Yorùbá lágbàáyé, Yorùbá Council Worldwide ní àwọn ti wọ́gilé ipò kí ipò tí Ọba ní ilẹ̀ Yorùbá fi Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo jẹ nítorí bí ó ṣe kùnà láti tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ àwọn Ọba aládé ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ .

Ìkéde yìí ló wà nínú àtẹjáde tí Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Ààrẹ Ọba Oladotun Hassan buwọ́lù, tó sì pe àkíyèsí Ọba Saka Metamilola, Olówu ti ìlú Òwu sí i.

Hassan ní ọ̀rọ̀ tí Obasanjo sọ sí àwọn lọ́balọ́ba lásìkò tó ń ṣe ìfilọ́lẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe kan tó jẹ́ ti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Mákindé ló jẹ́ àpèjúwe ìwùwàsí ológun tó ń bá àwọn ọmọdé sọ̀rọ̀, tí kò sì ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ilẹ̀ Yorùbá.

” A ń pa á lásẹ pé a ti wọ́gilé gbogbo ipò kí ipò tí Ọba aládé fi Obasanjọ jẹ, pàápàá tí Balógun ti ìlú Òwu lẹ́yìn tí Obasanjọ kọ̀ láti tọrọ àforíjìn.

“ Ọ̀rọ̀ tó wáyé ní LAUTECH ló jẹ́ ọ̀rọ̀ tó dójútini púpọ̀ , kí èèyàn pàṣẹ bí Ọgá ilé ẹ̀kọ́ tó ń bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ̀rọ̀.

“ Àwọn lọbalọba, orí adé ńlá ni àwọn Ọba yìí. A kò lè tẹwọgba iwuwasi yìí.

Ààrẹ Ọba Hassan wá rọ gbogbo ọmọ káàárọ ojíire, ọdọ, ìyá lọja àti àwọn olórí wọn láti tẹlé àṣà náà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here