Sùrutù l’Abeokuta níbi ìfẹ̀hónúhàn lórí ikú tó pa Mohbad

Sùrutù l’Abeokuta níbi ìfẹ̀hónúhàn lórí ikú tó pa Mohbad

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò tọ́ kí màjèṣín tojú òbí rọ̀run.Ìbànújẹ́ ayérayé ni.
Ẹsẹ̀ kò gba èrò lónìí ọjọ́
Ìṣẹ́gun nílùú Abẹ́òkúta nígbà tí àwọn ọ̀dọ́, pàápàá àwọn olólùfẹ́ orin tàkasúfèé jáde lọ́pọ̀ yanturu láti ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn àlàáfíà lórí ikú Ilerioluwa Ọladimeji Alọba tí ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ mọ̀ sí Mohbad.

Gbàgede eré ìdárayá tí wọ́n ń pè ní Skating Ground, èyí tó wà ládojúkọ Post Office, Ibara nílùú Abẹ́òkúta ni ìwọ́de náà ti wáyé.

Ohun tí a gbọ́ ni pé, nǹkan bí aago mẹ́wàá àárọ̀ ni ètò ọ̀hún bẹ̀rẹ̀, níbi tí àwọn ọ̀dọ́ tí ń pè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú Mohbad náà.

Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn olórin ọmọ bíbí ìlú Abẹ́òkúta nní, Adeyinka Adeboye tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Boye Best lo léwájú ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ọ̀hún.

Níbẹ̀ ni wọ́n ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó lábẹ́ Gómìnà Babajide Sanwo-Olu, ọ̀gá ọlọ́pàá orílẹ-èdè Nàìjíríà, Kayọde Ẹgbẹtokun láti má ṣe jẹ́ kí ikú Mohbad lọ lásán.

Boye Best ni gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú olóògbé náà ni wọ́n gbọdọ̀ fojú winnà òfin orílẹ-èdè Nàìjíríà, nítorí pé ọ̀kan pàtàkì lára àwọn tí yóó gbé ògo orílẹ-èdè yìí sókè ni wọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò.

Kò dín ní ẹgbẹ̀rún méjì àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n kórajọ láti fẹ̀hónúhàn lónìí, tí àwọn òṣìṣẹ́ agbófinró sì wà níbẹ̀ láti dáàbò bo àwọn èèyàn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here