Ẹnìkan fẹ́ máa lò fídíò ìhòhò mi gba owó –Lizzy Jay

Ẹnìkan fẹ́ máa lò fídíò ìhòhò mi gba owó –Lizzy Jay

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní èèyàn tó bá dákẹ ,tara rẹ̀ yóò ba dákẹ́ pẹ̀lú,ní bayìí, olókìkí adẹ́rìnínpòṣónú, Adebola Adeyeba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Lizzy Jay tàbí Omo Ibadan ti ké gbàjarè sí àwọn Nàìjíríà láti gba òun kalẹ̀ lọ́wọ́ ènìyàn kan tó fẹ́ máa fi àwòrán ìhòhò òun gba owó lọ́wọ́ òun.

Nínú fídíò kan tí Lizzy Jay gbé sórí Sítágíràmù rẹ̀ ló ti fẹ̀sùn kàn pé láti bí ọjọ́ mẹ́ta ni ẹnìkan ti ń pe òun, tó sì tún ń tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ sí òun pé òun ní àwọn àwòrán ìhòhò òun lọ́wọ́.

Ọmọ Ibadan ní nǹkan tí ẹni náà ń gbìyànjú láti ṣe ni láti fi fídíò náà gba owó lọ́wọ́ òun àmọ́ òun kò ṣetán láti san kọ́bọ̀ fún ẹnikẹ́ni.

Báwo ni ẹni náà ṣe ní fídíò ìhòhò Lizzy Jay?
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí ẹni náà ṣe ní fídíò ìhòhò rẹ̀ lọ́wọ́, Lizzy Jay ṣàlàyé pé ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni òun ri pé ẹnìkan ń gbìyànjú láti wọ inú àwọn àkáǹtì òun lórí ayélujára.

Ó ní èyí ló mú kí òun pàrọ̀ e-mail tí òun ń lò lórí Facebook àti Instagram òun láti ìgbà náà ṣùgbọ́n òun kò yọ ọ́ kúrò lórí Snapchat òun.

Lizzy Jay ní bí oṣù mélòó sẹ́yìn ni ó rẹ òun tí òun sì pe dókítà òun láti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó ń ṣe òun fún-un.

Ó ní dókítà kọ ogun àti abẹ́rẹ́ tí òun yóò lò láti fi yanjú àwọn nǹkan tó ń ṣe òun àmọ́ àwọn oògùn tí wọ́n kọ fún òun láti lò gbòsì lára òun.

Ó ní àwọn kòkòrò bẹ̀rẹ̀ sí ní yọ sí òun lára àti ní ojú ara òun àti pé ẹ̀jẹ̀ ń dà ní ojú ara òun.

Ó ṣàlàyé pé èyí ló mú òun ṣe fídíò ojú ara òun láti fi ránṣẹ́ sí dókítà tó kọ oògùn náà fún òun láti mọ bí nǹkan náà ṣe pọ̀ tó.

Ó fi kun pé Snapchat ni òun lò láti ṣe fídíò náà tí òun kò mọ̀ pé ẹnìkan wà tó ti ní àkáǹtì Snapchat òun tí ó sì fi fídíò náà sórí fóònù rẹ̀.

Lizzy Jay tẹ̀síwájú pé onítọ̀hún ti kọ́kọ́ pe òun pé òun ní fídíò ìhòhò òun lọ́wọ́ àti pé òun yóò gbé fídíò náà sórí ayélujára.

Ó ní kò pẹ́ ló tún pe òun pé òun ti gbé fídíò náà sórí Instagram pé kí òun lọ wò ó àmọ́ kò pẹ́ tó fi pa fídíò náà rẹ̀ níbẹ̀.

Ó fi kun pé ẹni náà dúnkokò mọ́ òun pé tí òun kò bá ṣe nǹkan tí òun ń fẹ́, òun máa lọ gbé fídíò náà sórí TikTok fún gbogbo ayé láti wò.

Lizzy Jay ní gbogbo nǹkan tó wà ní ìkáwọ́ òun ni òun máa ṣe láti ri pé ọwọ́ tẹ ẹni náà nítorí àìsàn tó ṣe àkóbá fún àgọ́ ara òun ló fẹ́ lò láti fi gba owó lọ́wọ́ òun.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here