Òògùn owó ni mo fẹ́ fi àwọn ọ̀rẹ́ méjì tí mo pa ṣe— Ọ̀daràn lahùn

Òògùn owó ni mo fẹ́ fi àwọn ọ̀rẹ́ méjì tí mo pa ṣe— Ọ̀daràn lahùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bauchi ti mú Ọgbẹni Ibrahim Umar, ẹni ogójì ọdún, tó pa àwọn òṣìṣẹ́ méjì níléeṣẹ́ kan tó wà lágbègbè Gamawa, níjọba ìbílẹ̀ Gamawa, níìpínlẹ̀ Bauchi.

Àwọn méjèèjì ọ̀hún tí wọ́n pàdé ikú òjìji láti ọwọ́ ọ̀daràn náà ni: Kabiru Idi, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì àti Bato Ali, ẹni ọdún méjìdínlógún.

Òun tí a gbọ́ ni pé Ibrahim tí í ṣe ọmọ ìlú Ungogo, lọ sílùú Taranka, níjọba ìbílẹ̀ Gamawa, láti lọ̀ọ́ hùwà láabi ọ̀hún, tọ́wọ́ sì tẹ̀ ẹ́ lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ ibi ọhún tán.

Ọ̀gbẹ́ni Adamu, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta kan tó ń gbé nílùú Taranka, níjọba ìbílẹ̀ Gamawa yìí kan náà, ló lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá agbègbè ọ̀hún láti lọ fẹjọ́ sùn wọn pé àwọn kò tí ì rí àwọn òṣìṣẹ́ méjèèjì táwọn ń wá láti nǹkan bíi oṣù kan sẹ́yìn .

Àtẹ̀jáde kan tí Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Ọ̀gbẹ́ni Mohammed Wakili, fi síta lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2023 yìí ni wọ́n ti sọ pé ìwádìí ìjìnlẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ibrahim ló pa àwọn méjèèjì ọ̀hún láti lò wọ́n fún ètùtù ọlà.

‘Lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá gbá a mú tán, wọ́n lọ̀ ọ́ yẹ ilé rẹ̀ wò, wọ́n sì bá gálọ́ọ̀nù ńlá kan tí ẹ̀jẹ̀ kún inú rẹ̀ fọ́fọ́, èyí tí wọ́n gbàgbọ́ pé ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni tó pa ló wà níbẹ̀.

Lójú-ẹsẹ̀ ni wọ́n ti jù ú sáhàámọ, láti lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwádìí wọn.

Ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá ló ti jẹ́wọ́ pé lóòótọ́, òun lòun pa àwọn èèyàn ọ̀hún láti fi wọ́n ṣòògùn owó. Lẹ́yìn náà ló mú àwọn ọlọ́pàá lọ síbi tó sìnkú wọn sí.

Wọ́n ti hú òkú àwọn èèyàn náà jáde, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti fìdí òótọ̀ múlẹ̀.

Àwọn ọlọ́pàá ti gbé òkú àwọn èèyàn ọhún fáwọn èèyàn wọn, kí wọ́n lè lọ ṣètò ìsìnkú wọn. Bákan náà ni wọ́n láwọn máa fojú ọdaràn náà balé -ẹjọ́ lópin ìwádìí àwọn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here