Kò pọndadan ká lo Àmọ̀tẹ́kùn fún ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀yọ́- Àjọ elétò ìdìbò

Kò pọndadan ká lo Àmọ̀tẹ́kùn fún ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀yọ́- Àjọ elétò ìdìbò

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní ẹni tó wẹjú ni ẹ̀rù n bà.
Àjọ elétò ìdìbò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (OYSIEC), ti sọ pé àwọn kò níí i ṣàmúlò ikọ̀ elétò ààbò ilẹ̀ Yorùbá tá a mọ̀ sí Àmọ̀tẹ́kùn fún ètò ààbò níbi ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó ń bọ̀.

Alága àjọ náà, Isiaka Ọlagunju, ló fìdí èyí múlẹ̀ lásìkò àbẹwò tó ṣe sí Correspondents’ Chapel), ìyẹn ẹ̀ka ẹgbẹ́ àwọn oníròyìn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (Oyo NUJ), nílé ẹgbẹ́ wọn tó wà ní Òpópónà Àgọ́ Tapa, ní Mọkọla, n’Íbàdàn.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, “ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lòfin fún ní ojúṣe pàtàkì jù lọ láti pèsè ètò ààbò lásìkò ètò ìdìbò. Síbẹ̀síbẹ̀, a ti bèèrè fún àtìlẹ́yìn àwọn elétò ààbò mí-ìn bíi sífú dìfẹǹsì, àwọn aláàmójútó ọgbà ẹ̀wọ̀òn, àti bẹ́ẹ̀ , bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣùgbọ́n a kò pe àwọn Àmọ̀tẹ́kùn nítorí àwọn èèyàn kò ní nígbàgbọ́ nínú wọn nígbà tó jẹ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló ni wọ́n, a ò sì fẹ́ nǹkan tó máa tàbùkù ètò ìdìbò yìí ”.

Ọkùnrin amòfin àgbà yìí fi kún un pé “a ò lè torí pé ẹgbẹ́ PDP tó ń ṣèjọba ló yàn wá sípò yìí, ká wá sọ pé ẹgbẹ́ PDP ló gbọdọ̀ wọlé ìdìbò. Ààyè pé à ń kọ ìbò fún ẹgbẹ́ òṣèlú kan ti kọjá lọ, ẹgbẹ́ tí àwọn aráàlú bá dìbò fún jù lọ ló máa wọlé ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà yìí.

Ààrẹ Ọlagunju fìdí rẹ̀ múlẹ̀ síwájú pé àwọn èèyàn tí kò dín ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) lajọ náà yóò gbà gẹ́gẹ́ bíi àwọn òṣìṣẹ́ tí yóò ṣètò ìdìbò ọ̀hún, àti pé láìpẹ́ làwọn yóó ṣàyẹ̀wò fáwọn olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú kọ̀ọ̀kan.

Tẹ́ ò bá gbàgbé, láìpẹ́ yìí làjọ OYSIEC kéde ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, (27) oṣù Kẹrin, ọdún 2024, gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìdìbò àwọn ìjọba ìbílẹ̀ gbogbo níìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Díẹ̀ lára àwọn tó kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú alága àjọ elétò ìbò ìpínlẹ̀ yìí ni Ọ̀mọ̀wé Babatunde Adeniyi, Ọ̀gbẹ́ni Kunmi Agboọla àti Emmanueli Ọlanrewaju.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here