Ẹni Olúbàdàn kàn ṣàbẹ̀wò sílé Olúbàdàn àná

Ẹni Olúbàdàn kàn ṣàbẹ̀wò sílé Olúbàdàn àná

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọba Olakulehin Owólabí tí oyè Olúbàdàn kan ṣe àbẹ̀wò sí ilé Ọba Mahood Lekan Balogun Olubadan ti ilẹ̀ Ìbàdàn tó gbé ṣe láìpẹ́ yìí.

Nígbà tó ń ṣàlàyé ìdí àbẹwò náà, Òsì Balógun, Ọba Gbadamosi Adebimpe tó gba ẹnu Ọba Olakulehin Owolabi sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé ṣaájú kí Kábíyèsí Ọba Mahood Lekan Baloygun tó gbéṣẹ̀ ni ara Kábíyèsí Olakulehin ò ti le.

Ó ní “ Ní báyìí tí ara wọn ti mú okun ló fàá tí wọ́n fi ṣàbẹ̀wò yìí nítorí pé ọ̀rẹ́ ni àwọn méjèèjì jẹ́ .”

Òsì Balógun tún ṣàlàyé pé ìgbà àkọ́kọ́ tí ẹni tí oyè Olúbàdàn kan yóò ṣe àbẹ̀wò sí ilé Olúbàdàn tó gbéṣẹ̀ nílùú Ìbàdàn nìyí.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ rẹ̀, Sẹ́nẹ́tọ̀ Kola Balógun tó jẹ́ àbúrò Olúbàdàn àná fi ìdùnnú rẹ̀ hàn, ó sì ṣàpèjúwe ìṣèjọba Ọba Mahood Lekan Balógun gẹ́gẹ́ bíi èyí tó mú àlàfíà bá ìlú Ìbàdàn.

Ó wá rọ Ọba Owólabí Olakulehin láti jẹ́ kí àlàfíà tó ti ń jọba nílùú Ìbàdàn tẹ̀síwájú lẹ́yìn ìgbà tó bá ti dé orí oyè gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn tuntun.

Tí ẹ kò bá gbàgbé, lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 yìí ni gbogbo awuyewuye tó ti ń wáyé lórí ẹni tó yẹ kó jẹ oyè Olúbàdàn dópin lẹ́yìn ti àwọn afọbajẹ fọwọ́ sí Owólabí Ọlakulẹhin gẹ́gẹ́ bíi ọmọ oyè tuntun.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó hàn pé àgbà ti dé sí Olúbàdàn tó ń bọ̀ lọnà ọ̀hún látàrí bó ṣe rọra ń tẹ̀ kẹ́jẹ́ kẹ́jẹ́ ní ṣe làwọn èèyàn ń kí i ní mẹsan-an mẹ́wàá, tí wọ́n ń ṣàdúrà fún un pé yóó lo ipò náà kánrin.

Wàyí ò, ìgbìmọ̀ àpapọ̀ Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn ti fẹnu kò láti fi Ọba Olakulehin Owolabi jẹ Olúbàdàn tuntun, àmọ́ kò tí ì hàn dájú ọjọ́ tí yóó tẹri gba adé Olúbàdàn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here