Ọkùnrin kan tó fẹ ìyàwó méje lẹ́ẹ̀kan náà sọ pé kò sí owú láàrin wọn
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ohun tó bá wolówó ní-ín fowó rẹ̀ rà.N tó bá sì wu ọmọ ọ́n jẹ, kì í run ọmọ nínú ni ọ̀rọ̀ Ssaalongo Nsikonenne Habib Ssezzigu tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí gba orí ayélujára lẹ́yìn tó fẹ́ ìyàwó méje ní ọjọ́ kan náà.
Lára obìnrin méje ní a ti rí ẹ̀gbọ́n àti àbúrò, tí ìgbéyàwó ọ̀hún sì wáyé ní Abule Bugerek lórílẹ̀ èdè Uganda lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹsàn án ọdún 2023.
Orúkọ àwọn ìyàwó náà ni Mariam, Madinah, Aisha, Zainabu, Fatuma, Rashida àti Musanyusa, tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́ tó ti wà pẹ̀lú rẹ̀ fún ọdún méje.
Nínú àtẹ̀jáde kan tó wà lórí ayélujára, sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀ Caleb Canaan ní ayẹyẹ ìgbéyàwó bẹ̀rẹ̀ ní ago mẹ́jọ àárọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gbé àwọn ìyàwó náà lọ ilé oní dìrí.
“Lẹ́yìn tí ọkọ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ ṣe ìbúra, Nsikonenne àti àwọn ìyàwó rẹ̀ méje gun kẹ̀ẹ̀kẹ̀ káàkiri abúlé bí Kalagi, Kasana àti Nakifuma kí wọ́n tó lọ ilé wọn ní ago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ .”
Nsikonenne ra ọkọ̀ bọ̀gìnì tuntun fún àwọn ìyàwó náà, tó sì rọ àwọn ìyàwó náà láti fẹ́ ẹ pẹ̀lú òtítọ́ inú.
“Kò sí owú láàrin àwọn ìyàwó mi. Mo mọ wọ́n ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí mò ṣì pinnu láti fẹ ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú wọn ní ẹ̀kanáà láti ní ìdílé aláyọ̀.”
Nsikonenne ní òun yóò tún fẹ́ ìyàwó sí i lọ́jọ́ iwájú
“Ọmọdé sì ni mí àti pé lọ́jọ́ iwájú, tí Ọlọ́run bá fẹ́ máa fẹ́ ìyàwó sí i .”
Bàbá ọkọ, Hajj Abdul Ssemakula ní fífẹ́ ìyàwó púpọ̀ ló jẹ́ nǹkan tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ mọ̀lẹ́bi wọn.
“Bàbá tó bí bàbá mi fẹ́ mẹ́fa, Bàbá mi fẹ́ márùn un, èmi gan fẹ́ fẹ́ mẹ́rin tí a jọ ń gbé ilé kan náà.”
Habib ló ti wá fi ìtàn balẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tó fẹ́ ìyàwó méje lẹ́ẹ̀kanáà lórílẹ̀ èdè Uganda.