Gómìnà Èkìtì pàṣẹ kí kọmísánnà rẹ̀ tuntun kan ó lọ̀ọ́ sinmi ná

Gómìnà Èkìtì pàṣẹ kí kọmísánnà rẹ̀ tuntun kan ó lọ̀ọ́ sinmi ná

Ọrẹ Òtítọ́jù

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, Biọdun Oyebanji, ti ní kí kọmiṣanna fún ọrọ̀ oyè jíjẹ ni ipinlẹ náà, Ọlaiya Atibioke, lọ máa sinmi nílé ná.

Ẹsùn àfojúdi ni wọ́n ní Gómìnà fi kan ọkùnrin náà, nítorí bó ṣe kúrò níbi ètò kan tí wọ́n ń ṣe láì gbaaye.

Olùdámọ̀ràn Gómìnà lórí ètò ìròyìn, Yinka Oyebọde, tó fi ọrọ̀ náà léde sọ pé ìpàdé apejẹ kan ni wọ́n ṣe, Gómìnà pàápàá sì wà níbẹ̀ títí tó fi wá sópin, ṣùgbọ́n Atibioke fi ibẹ̀ sílẹ̀ láì tọrọ ààyè.

Ninu atẹjade naa lo ti ni, “Gomina ti fofin de Atibioke, latari bo ṣe kuro nibi eto apejẹ ọlọjọ mẹta ti wọn ṣe fawọn igbimọ ijọba ipinlẹ Ekiti, atawọn akọwe agba ni gbọngan nla Bishop Adetiloye, Trade Fair Complex, Ado-Ekiti, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

Loju-ẹsẹ nibẹ lo si ti paṣẹ pe ko lọọ rọọkun nile fun odidi ọsẹ meji”.

Lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ti eto naa ti bẹrẹ ni gomina ti wa nikalẹ titi to fi wa sopin.

Ṣaaju ọjọ ti eto naa yoo bẹrẹ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn ni Gomina Oyebanji yan awọn kọmiṣanna mọkandinlogun mi-in atawọn oludamọran mẹtala. Ọkan lara awọn kọmiṣanna tuntun ọhun ni Atibioke.

Wọ ni nigba to di nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ ti eto naa yoo pari, wọn ke si awọn kọmiṣanna atawọn akọwe agba nileeṣẹ ijọba to wa nibẹ lati wa maa fọwọ siwee lori bi eto naa ṣe lọ si. Aṣiri ọrọ tu nigba ti wọn pe orukọ Atibioke, ti ko sẹni to gbọ idahun rẹ.

Pẹ̀lú ìbínú ni wọ́n ní gómìnà fi he ẹ̀rọ amóhùndún-gbẹ̀mù, tó bèèrè kọmíṣọ́nnà ọ̀hún, ṣùgbọ́n tí kò gbúròó rẹ̀. Níbẹ̀ ni wọ́n ní gómìnà tí pàṣẹ pé kó lọ̀ọ́ dúró sílé fódidi ọ̀sẹ̀ méjì gbáko.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here