YIF gba Aare̩ Tinubu nímò̩ràn láti má se yanjú aáwò̩ Niger Republic pè̩lú o̩wó̩ líle
Alakoso Yoruba Indigenes Foundation ( YIF ), Dr Olumide Aderibole gba Aare̩ Tinubu ati awo̩n ajo̩ ECOWAS nimo̩ran pe ti okun ba n ho ruru ki awo̩n ma se wa ruru nipa ifipa gbajo̩ba to waye ni orileede olominira Niger.
Ninu atejade iroyin kan, ti Ọgbẹni Sanjo Olawuyi fowo si, Oludari awọn ibara-ẹni-sọrọ ati awọn ilana ti Yoruba Indigenes Foundation ( YIF ). Aderibole sọ pe “ lai bikita, ibara-eni- soro lọna ologun ni Niger Orile-ede olominira yoo ṣe afihan sinu: ipadanu nla ti awọn igbesi aye ati awọn ohun-ini ti awọn ara ilu alaiṣẹ ti Orilẹ-ede Niger.
O le yori si ki awon eeyan sa koja enu ala lai ba ofin mu; ibesile ti ajakale-arun ni Niger Republic, eyi ti yoo tan si awọn orilẹ-ede aladugbo wọn; yoo ja si ipadanu owo ti o po yanturu, eyi ti o le tumọ si awọn ọkẹ àìmọye; yoo fa ibajẹ ati rogbodiyan ilu ni Niger Republic; awọn iṣowo ati awọn iṣẹ-aje yoo ni ikolu lara; ebi ati irora yoo wo ilu wa. ”Alakoso YIF tẹ siwaju nipasẹ tito le̩se̩e̩se̩ nipa awọn ọna omiiran ti o le fi yanju aawo̩ – awọn ijiroro ti o kun fun iduna-dura, fifi ijoba awa ara wa fidihe sori isakoso, s̩is̩eto ibo ni orilẹ-ede naa.
Dr Aderibole gunle̩ o̩ro̩ pe̩lu imo̩ran yii – ti Alakoso Bola Tinubu ba ṣaṣeyọri ninu yiyanju aawo̩ ilu naa ni itubi inubi, oruko won yoo maa je kiko sile ninu iwe itan ayeraye.
Wole:Sanjo Olawuyi
Oludari Awọn ibaraẹnisọrọ ati Awọn ilana,Yoruba Indigenes Foundation.
*ATUMỌ ÈDÈ SÍ YORÙBÁ ***OMOBA LAWAL ONÍKẸ̀KẸ́ ÒRÌSÀ WÁLÉ AROLE OODUA **