Olùdásílẹ̀ ìjọ Fountain of Life Church, Taiwo Odukoya jáde láyé

Olùdásílẹ̀ ìjọ Fountain of Life Church, Taiwo Odukoya jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò sééyàn tí kò ní-ín kú, kò séèyàn tóko baba rẹ̀ kò ní-ín dìgbòrò. Olùdásílẹ̀ ìjọ Fountain of Life Church, pásítọ̀ Taiwo Odukoya ti jáde láyé.

Àwọn aláṣẹ ìjọ ọ̀hún ló fi ìkéde ìpapòdà rẹ̀ léde lójú òpó Facebook ìjọ náà.

Ìròyìn sọ pé àná, ọjọ́ keje, oṣù Kẹjọ, ọdún 2023 ni olùṣọ àgùtàn náà fi ayé sílẹ̀.
Àtẹ̀jáde náà ni “ Àwa ọmọ ìjọ Fountain of Life Church, ní gbígba àmúwá Ọlọ́run kéde ikú bàbá wa, olùkọ àti ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè Daniel Taiwo Odukoya tó jáde láyé lọ́jọ́ keje, oṣù Kẹjọ, ọdún 2023 nílẹ̀ Amẹ́ríkà.

“A ti gbà fún yín Ọlọ́run.”

“ Adúpẹ́ fún ìgbé ayé rere tí adarí wa gbé lókè èèpẹ̀.”

Ọjọ́ karùndínlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 1956 ní wọ́n bí Taiwo Odukoya nílùú Kaduna, níbi tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà.

Òun ni olùṣọ́àgùtàn àgbà ìjọ Fountain of Life Church tó wà ní Ìlúpéjú nílùú Èkó, tí iye àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ sì lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ.

Ọdún 1980 ni olóògbé náà pàdé ìyàwó rẹ̀, Bimbo Williams, tí wọ́n sí ṣe ìgbéyàwó lọ́dún 1984.

Lọ́jọ́ kẹwàá, oṣù Kejìlá, ọdún 2005, Bimbo Odukoya kú sínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú Sosoliso tó já lulẹ̀ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún lé méjì èèyàn mìíràn.

Lọ́dún 2010, Taiwo Odukoya fẹ́ ìyàwó míràn, Rosemary Simangele Zulu, tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè South Africa.

Àmọ́ nígbà tí yóò fi di oṣù Kọkànlá, ọdún 2021, ó pàdánù ìyàwó rẹ̀ kejì ọ̀hún ṣọ́wọ́ àrùn jẹjẹrẹ

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here