Àbọ̀dé Niger, Sanusi gba Tinubu nímọ̀ràn

Àbọ̀dé Niger, Sanusi gba
Tinubu nímọ̀ràn

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní n tá ò bá fẹ́ kò bàjẹ́,ó ní bí wọ́n ti í ṣe é.
Ọ̀gá àgbà báńkì àpapọ̀ ilẹ̀ wa nígbà kan, tó sì tún ti fìgbà kan jẹ́ Ẹmia ilẹ̀ Kano, Alaaji Sanusi Lamido Sanusi, ti ṣàbẹ̀wò sáwọn ṣọ́jà tí wọ́n gbàjọba lórílẹ̀-èdè Niger, bẹ́ẹ̀ ló sì ti lọ̀ọ́ jábọ̀ àbẹ̀wò pàtàkì rẹ̀ ọ̀hún fún Olórí orílẹ-èdè wa, Bọla Ahmed Tinubu.

Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Kẹjọ yìí ni Sanusi ṣàbẹ̀wò rẹ̀ ọ̀hún, tó sì jókòó ìpàdé bònkẹ́lẹ́ kan pẹ̀lú àwọn olórí ṣọ́jà tí wọ́n ń ṣèjọba lọ́wọ́ nílẹ̀ Niger ọ̀hún. Ìlú Niamey, tí í ṣe olú-ìlú orílẹ-èdè Niger ni wọ́n ti gbà á lálejò.

Bákan náà ni Sanusi ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé kì í ṣe Olórí àjọ Economic Community of West African States, ECOWAS, ìyẹn Tinubu, ló rán òun lọ sọ́hùn-ún, ó ní òun lo ìdánúsọ ara òun ni, gẹ́gẹ́ bíi èèkàn kan nínú ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí Tijjaniya, èyí ti ọ̀pọ̀ àwọn alátìlẹ́yìn ẹgbẹ́ nàà wà lórílẹ̀èdè Niger. Sanusi ló wà nípò Khalifa ẹgbẹ́ Tijjaniya ọ̀hún lọ́wọ́lọ́wọ́.

Nínú fọ́tò àti fídíò kan tó ń jà rànyìn lórí ayélujára, wọ́n ṣàfihàn Ṣanusi, níbi tó ti jókòó àpérò pẹ̀lú àwọn olórí ṣọ́jà Niger, àti bí wọ́n ṣe gba ọkùnrin náà tọwọ-tẹsẹ lásìkò àbẹwò rẹ̀. Sultan ti ìlú Damagaran wa lara awọn to kọwọọrin pẹlu Sanusi lọ sipade ọhun. Ipo kẹta ni ilu Damagaran yii wa laarin awọn ilu to tobi ju lọ nilẹ Niger.

Ninu ọrọ ṣoki kan to sọ fawọn oniroyin lori abẹwo rẹ ọhun, Sanusi ni: “Mo wa lati sọrọ ilaja ati ipẹtu-saawọ pẹlu olori ologun, Jẹnẹra Abdourahamane Tchiani, ni. Mo ti ba olori ijọba ologun naa sọrọ, ma a si lọọ fi abọ ajọsọ wa jiṣẹ fun Aarẹ Tinubu,” Amọ o fi kun ọrọ rẹ pe ki i ṣe ijọba tabi ECOWAS lo ran oun wa silẹ Niger.

Bi Ṣanusi ṣe pari ijiroro rẹ pẹlu awọn ṣọja naa ti wọn si sin in sọna, taara lo balẹ siluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, nibi to ti lọọ jiroro pẹlu Aarẹ Bọla Tinubu, wọn si tilẹkun mọri sọrọ, laṣaalẹ ọjọ Wẹsidee naa.

Bakan naa ni Sanusi sọ fawọn oniroyin l’Abuja pe: “Asiko yii ki i ṣe eyi ta a maa da ọrọ yii da ijọba nikan, ọrọ ifikunlukun ati igbọra-ẹni-ye gidi lo ṣẹlẹ yii. Awọn eeyan Naijiria ati ti ilẹ Niger gbọdọ fọwọ sowọ pọ lati wa ojuutu to maa ṣanfaani fun ilẹ Afrika lapapọ, to si maa ṣe tolori tẹlẹmu loore.

Nígbà ti wọ́n bèèrè bóyá ìjọba Nàìjíríà ló rán an lọ, Sanusi ní, “rara, ìjọba ò rán mi niṣẹ, àmọ́ mo fi ọ̀rọ̀ àbẹwò mi tó àwọn aláṣẹ wa létí, wọ́n sì mọ̀ pé mò ń lọ sọ́hùn-ún, ṣùgbọ́n ìdánúṣe ara mi ni mo fi lọ, èmi sì ni mo kàn sí àwọn tí mo mọ̀ lọ́hùn-ún tí wọ́n fi ní kí ń máa bọ̀. Gbogbo nǹkan tó bá wà níkàápá mi ni mà á ṣe láti yanjú ìṣòro náà, torí nǹkan tó yẹ kí ń ṣe gẹ́gẹ́ bíi adarí kan ni.” Sanusi.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here