Bàbá ogójì ọdún tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́ta lò pọ̀ ti rẹ́wọ̀n he

Bàbá ogójì ọdún tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́ta lò pọ̀ ti rẹ́wọ̀n he

Fẹ́mi Akínṣọlá

Èèyàn tó bá ṣe ohun tẹ́nìkan kò ṣe rí, kò láìfì kójú onítọ̀hún ó rí n tẹ́nìkan kò rí.
Ṣé wọ́n ní ràdàràdà kìí báwọn lágbà,nì báyìí,wọ́n ti wọ́ Ọ̀gbẹ́ni Abdulahi Lawal, ẹni ogójì ọdún lọ iwájú Onídàájọ A.B Olagbegi Adelabu, tilé-ẹjọ́ Májísírétí kan tó wà nílùú Ikorodu, ní ìpínlẹ̀ Èkó. Ẹsùn tí wọ́n fi kàn án ni pé ó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́ta kan tó jẹ́ ọmọ aráalé rẹ̀ sùn.

Ọlọ́pàá olùpẹ̀jọ́, Abilékọ Ọlawumi Ọsinbajo, tó fojú Lawal balé-ẹjọ́ sọ pé inú oṣù Kẹfà, ọdún yìí, ní Lawal hùwà rádaràda náà l’Ójúlé kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, Òpópónà Owutu, lágbègbè Agric, nílùú Ikorodu, ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Ó ní ṣe ni Lawal gbé ọmọ ọdún mẹ́ta ọ̀hún wọnú yàrá rẹ̀ lákòókò tó ń bá a ṣeré lọ́wọ́ níwájú òbí rẹ̀, tó sì fipá bá a sùn.

Nígbà tí màmá ọmọ ọhún ń wá a káàkiri, tó sì ń pariwo rẹ̀ lọmọ náà jáde nínú yàrá Lawal, tí ẹjẹ́ sì wà lára aṣọ rẹ̀ yánna- yànna

Lójú-ẹ̀sẹ̀ ní màmá ọmọ ọ̀hún ti lọọ fọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá agbègbè náà létí, tí àwọn agbófinró yìí sì lọọ fọwọ́ òfin mú un nílé rẹ̀.

Gbogbo ẹsùn tí ọlọ́pàá náà fi kàa Lawal pátá ló ní òfin ìlú Èkó kò fààyè gbà rárá.

Adájọ́ ilé-ẹjọ́ náà, Abilékọ A.B Olagbegi, kò tiì tẹ́tí gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ rárá. Ó ní kí wọ́n lọ̀ọ́ gbà àmọ̀rán wà lórí ẹjọ́ náà lọdọ àjọ kan tó ń gba ilé-ẹjọ́ nímọ̀ràn, ‘Lagos State Directorate Of Public Prosecution’ DPP.

Bákan náà ló ní kí wọ́n lọ̀ọ́ jù ú sọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kiríkirì tó wà nílùú Èkó, títí ìgbẹ́jọ́ máa fi wáyé.

Ó sún ìgbẹ́jọ́ sọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2023 yìí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here