Àwọn ọmọ-ọwọ́ nìkan ni ọyàn mímu wà fún – ìyàwó Mákindé

Àwọn ọmọ-ọwọ́ nìkan ni ọyàn mímu wà fún – ìyàwó Mákindé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ẹ̀là lọ̀rọ̀ bí a ò bá làá , kìí yéni ní báyìí,Ìyàwó Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Abilekọ Tamunominini Makinde, ti ṣàpèjúwe ọyàn gẹ́gẹ́ bíi oúnjẹ tó dáa, tó dùn, tó ṣara lóore, tó sì dáa fún gbogbo èèyàn láti máa mu.

Àmọ́ ṣáá, àwọn ọmọ ọwọ́ nìkan níyàwó Gómìnà yìí tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bíi ẹni tó nílò oúnjẹ aṣara lóore náà.

Níbi ètò ọlọ́dọọdún tí wọ́n fi ṣàmí ayẹyẹ fífún ọmọ lọ́yàn lo ti sọ̀rọ̀ náà n’Íbàdàn, l’Ójọ́bọ, ọjọ́ kẹta, oṣù Kẹjọ, ọdún 2023 yìí.
Nígbà tó n sọ pàtàkì fífún ọmọ lọ́yàn nìkan fún àwọn obìnrin, Abilékọ Mákindé fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ọyàn loúnjẹ tó dáa jù tí ìkókó gbọdọ̀ mu láìjẹ oúnjẹ mí-ìn rárá láàrin oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ tí wọ́n bí i sáyé.

Àkòrí ayẹyẹ tọdúun yìí ló dá lórí bí àwọn òṣìṣẹ́ ṣe lè máa fún ọmọ wọn lọ́yàn dáadáa.

Ó ṣàpèjúwe omi ọyàn gẹ́gẹ́ bíi omi tó mọ́, tó sì jẹ́ oúnjẹ aṣaralóore tó dáa jù fáwọn ọmọ ọwọ́.

O wáá dúpẹ lọ́wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Ẹnjinnia Ṣeyi Mákindé, fún bó ṣe ń sàtìlẹyìn fún àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé ní ìpínlẹ̀ náà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here