Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fẹ́ẹ́ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ọdún eégún ọlọ́dọọdún

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fẹ́ẹ́ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ọdún eégún ọlọ́dọọdún

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní tẹni n tẹni, ìran ọlọ́jẹ̀ ló lẹ̀kún, olórò ló lawo.
Yàtọ̀ sí ọdún eégún tó máa ń wáyé lọdọọdun lásìkò tó yàtọ síra wọn nílùú kan sikeji káàkiri ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ìjọba Gómìnà Ṣeyi Mákindé ti pinnu láti ní ọdún eégún kan lọtọ tí yóó jẹ́ tìjọba.

Gbogbo àwọn atọkùn eégún tá a mọ̀ sí Alágbàáà jákè -jàdò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni wọ́n ti fara mọ́ ìpinnu ìjọba yìí nínú ìpàdé tí àwọn aṣojú ìjọba ṣe pẹ̀lú wọn l’Ojọbọ, ọjọ́ kẹta, oṣù kẹjọ, ọdún 2023 yìí.

Nígbà tó ń kéde ìpinnu ọhún fún gbogbo ayé gbọ́, Kọmiṣanna fétò ìròyìn, àṣà àti irinna afẹ níìpìnlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀mọ̀wé Wasiu Ọlatubọsun, sọ pé ìjọba yóò ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ọdún eégún, níbi tí gbogbo eégún ìpínlẹ̀ náà yóó ti máa dá àwọn lárayá, níbì kan náà, lọ́jọ́ kan náà.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, “ Kí àwọn eégún máa fi eré dá àwọn èèyàn láyayá jẹ́ nǹkan ọ̀tun, èyí tí kò tí ì sírú ẹ̀ níbi kan rí lórílèdè yìí. Èyí yóò ṣàfihàn wa gẹ́gẹ́ bíi àwòṣe rere fáwọn ìpínlẹ̀ yòókù gẹ́gẹ́ bíi àkọmọ̀nà ìpínlẹ̀ yìí tó sọ pé

“Ajíṣe bíi Ọ̀yọ́ là á rí …”

“ Ṣíṣe irú nǹkan báyìí yóò jẹ́ ọ̀nà tí owó yóò fi máa wọlé sápò ìjọba, nítorí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ yóó lè máa kó owó wọn wá láti wòran àwọn eégún láti ilẹ̀ òkèèrè káàkiri”.

Yàtọ̀ sí pé gbogbo àwọn alágbàáà tó wà níbi ìpàdé ọhún ni wọ́n fara mọ́ ìpinnu ìjọba náà, gbogbo wọn ni wọ́n ti ṣèlérí pé àwọn yóó ṣàtìlẹ́yìn fún ìjọba lórí ìpinnu náà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here