Atótónu parí, ìdájọ́ ló kù – ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ

Atótónu parí, ìdájọ́ ló kù – ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ lorilẹede Nàìjíríà ní gbogbo atótónu tó yẹ kó wáyé lórí ẹjọ́ tí olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Alhaji Atiku Abubakar pè tako ìjáwé olúborí Tinubu ti parí.

Ìgbìmọ̀ adájọ́ ẹlẹ́ni márùn-ún náà ni gbogbo ètò ìgbẹ́jọ́ ti parí lẹ́yìn tí wọ́n ka àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ tí àwọn olùpẹjọ́ pè níbi ìjókòó ìgbẹ́jọ́ tó wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹjọ ọdún 2023.

Alága ìgbìmọ́ ọ̀hún, Adájọ́ Haruna Tsamani sọ wí pé ìgbìmọ̀ oludajọ náà yóò fi ọjọ́ ìdájọ́ ti wọn ba yan to gbogbo ìlú létí ní kété tí wọ́n bá ti fẹnukò lórí rẹ̀.

Atiku Abubakar ń pe ẹjọ́ tako bí àjọ elétò ìdìbò Nàìjíríà, Inec ṣe kéde Bola Tinubu gẹ́gẹ́ bí olúborí ìdìbò Ààrẹ tó wáyé loṣu Kejì ọdún 2023.

Bákan náà ni olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi náà ní òun kò gbà pé Tinubu ló gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.

Wọ́n ń fẹ̀sùn kàn pé màgòmágó wà nínú ètò ìdìbò náà tí wọ́n sì ń rọ ilé ẹjọ́ láti wọ́gilé ìdìbò ọ̀hún, kí INEC gba ìwé ẹ̀rí mo yege tí wọ́n ti ṣáájú fún Tinubu kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.

Ṣaájú ni ìgbìmọ̀ náà ti ní kí gbogbo àwọn olùpẹjọ́ ìyẹn Atiku Abubakar àti Peter Obi tẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party wá sọ gbogbo ohun tí wọ́n bá ní lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here