Akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta tó fipábánilòpọ̀ rí ẹ̀wọ̀n he

Akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta tó fipábánilòpọ̀ rí ẹ̀wọ̀n he

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ẹjọ́ gíga ìpńlẹ̀ Kwara tó fi ìlú Ilorin ṣe ibùjókòó ti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta kan lẹ́wọ̀n fẹ́sùn wí pé wọ́n fipá bá pá ìbátan ọ̀kan nínú wọn lòpọ̀.

Adájọ́ Adenike Akinpelu ní ilé ẹjọ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ènìyàn náà jẹ̀bi ẹ̀sùn méjì tí wọ́n kà sí wọn lọ́rùn.

Ní agbègbè Adangba, ìjọba ìbílẹ̀ Ilorin East ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìfipábánilòpọ̀ náà ti wáyé.

Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, Omotosho Yahaya, Mustapha Ahmed àti Mustapha Ridwan ni wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Ìròyìn ní Yahaya ló ránṣẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjì láti wá fipá bá arábìnrin náà lòpọ̀ nígbà tó wà nínú ilé pẹ̀lú rẹ̀.

Adajo Akinpelu sọ àwọn afurasí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún fẹ́sùn ìfipábánilòpọ̀ àti ẹ̀wọ̀n ọdún méjì mìíràn fẹ́sùn lílẹ̀dí àpòpọ̀ láti fi hu ìwà àìda.

Bákan náà ni ilé ẹjọ́ tún ní kí wọ́n san owó ìtanràn ẹgbẹ́rùn lọ́nà àádọ́ta náírà ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.

Adájọ́ ní fúnra àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni wọ́n jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ àti pé sísọ wí pé arábìnrin tí wọ́n bá lòpọ̀ náà jẹ àwọn lówó jẹ́ ọ̀nà láti fẹ́ sá fún ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìgbẹ́jọ́ náà, olùpẹjọ́, Muslimat Suleiman láti iléeṣẹ́ ètò ìdájọ́ ìpínlẹ̀ Kwara ní ìdájọ́ náà dùn mọ́ àwọn pé àwọn afúrasí náà kojú ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here