Ìjọba mi kò káwọ́ gbera látàrí ìpèníjà tí àwọn ènìyàn ń kojú lọ́wọ́lọ́wọ́–Ààrẹ Tinubu

Ìjọba mi kò káwọ́ gbera látàrí ìpèníjà tí àwọn ènìyàn ń kojú lọ́wọ́lọ́wọ́–Ààrẹ Tinubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣe àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní ọmọ onílùú tòótọ́ kò ní-ín fẹ́ kó tú, àti pé ohun a fẹ̀sọ̀ mú kìí bàjẹ́,ohun a bá fagbára mú koko ní-ín leí alẹ́.
Ní ọjọ́ Ajé ni Ààrẹ Orílẹ̀ yìí Tinubu bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìpèníjà tí àwọn ènìyàn ń kojú l’ati ìgbà tí wọ́n ti yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù.

Àwọn kókó ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ dá lé lórí ni ètò ọrọ̀ ajé, ẹ̀kọ́ àtàwọn nǹkan mìíràn.

Tinubu ní òun mọ́ gbogbo ìdojúkọ tí àwọn ènìyàn ń kojú báyìí láti ìgbà tí wọ́n ti yọ ìrànwọ́ orí bẹntiróòlù.

Ààrẹ ní ìjọba òun kò sùn tí àwọn sì ń gbé gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ láti mú ìdẹ̀kùn bá àwọn ènìyàn.

Ó ṣàlàyé pé ìjọba òun ti ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ àti ti ìbílẹ̀ láti ri dájú pé gbogbo ẹ̀ka ni ìrọ̀rùn ti wáyé.

Ìpèsè iṣẹ́
Tinubu ní ìjọba òun ti ya ₦75bn kalẹ̀ láti pèsè iṣẹ́ tó dára fún àwọn ènìyàn àti pé láàárí oṣù Keje ọdún 2023 sí oṣù Kẹta ọdún 2024 ni yóò wáyé.

Ó ní èròńgbà àwọn ni láti pèsè ẹ̀yáwó bílíọ̀nù kan náírà fáwọn iléeṣẹ́ márùndíndínlọ́gọ́rin láti bẹ̀rẹ̀ òwò tó máa mú ìgbéga bá okoòwò wọn àti ìpèsè iṣẹ́ fún àwọn ará ìlú.

Bákan náà ló sọ wí pé àwọn yóò tún pèsè owó ₦125bn fún àwọn olókoòwò kékeré láti fi mú kí ẹ̀ká yìí gbèrú síi.

Ìpèsè oúnjẹ
Ààrẹ tún ṣàlàyé pé láti lè ri dájú pé oúnjẹ pọ̀ lọ́pọ̀ yanturu ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Tinubu ní àwọn ti ń bá àwọn àgbẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí ọ̀nà tí wọ́n máa gbà láti pèsè ọúnjẹ tó máa pọ̀ fún ará ìlú.

Ó ní òun ti pàṣẹ pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní pín àwọn oúnjẹ wooro tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ìgbà sáwọn ìdílé káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Bákan náà ló ní àwọn tún ti bẹ̀rẹ̀ sí ní pín ajílẹ̀ fáwọn àgbẹ̀ àti pé igba bílíọ̀nù náírà nínú ẹ̀yáwó tí àwọn fẹ́ gbà ni àwọn máa dà sí ètò ọ̀gbìn.

Ìpèsè ọkọ̀
Tinubu ní lára àwọn ìgbésẹ̀ tí ìjọba òun ń gbé ni ìpèsè ọkọ̀ kí lílọ bíbọ̀ àwọn ènìyàn le túnbọ̀ máa rọrùn síi.

Ó ní àwọn ń gbèrò láti ná ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù náírà láti fi ra àwọn ọkọ̀ 3,000 sí ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìbílẹ̀ láti máa fi gbé àwọn ènìyàn ní owó pọ́ọ́kú.

Ó ní àwọn ọkọ̀ náà ni èyí tó má máa lo afẹ́fẹ́ gáàsì dípò epo bẹntiróòlù àti pé àwọn máa bá àwọn iléeṣẹ́ ọlọ́kọ̀ dòwò pọ̀ láti mú ètò náà wá sí ìmúṣẹ.

Àlékún owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́
Ààrẹ tún ṣàlàyé pé àwọn ti ń bá àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ jíròrò láti sọ̀rọ̀ lórí owó oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́.

Ó ní kété tí àwọn bá ti fẹnukò lórí iye tí owó náà yóò jẹ́ ni àwọn yóò gbé àbá ìsúná síwájú ilé aṣòfin kí àwọn lè bẹ̀rẹ̀ sísan rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Bákan náà ló kan sáárá sí àwọn òṣìṣẹ́ pé àlékún ń bọ̀ lórí owó oṣù wọn láìpẹ́, pé kí wọ́n fi ọkàn balẹ̀ tó sì tún yin àwọn ilé iṣẹ́ aládani tó ti mú àlékún bá owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ wọn.

Ètó ẹ̀kọ́
Tinubu tún tẹ̀síwájú pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ nípa pípèsè ètó ẹ̀kọ́ tí kò ní gun àwọn ènìyàn lápá.

Ó ní ìjọba òun máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé kò sí akẹ́kọ̀ọ́ kankan tí yóò pa ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ tì nítorí àìsí owó tí yóò fi tẹ̀síwájú nítorí ẹ̀yáwó máa wà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni gbogbo ìpele.

Tinubu sọ ní ìkẹyìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé bí nǹkan yóò bá dára yóò kọ́kọ́ le ní ìbẹ̀rẹ̀ àti pé àsìkò tí nǹkan yóò le ni a wà yìí àmọ́ ìdẹ̀kùn ti dé tán.

Ó ní ó dá òun lójú pé àsìkò tí ohun gbogbo yóò dẹrùn fún àwọn ọmọ Nàìjíríà ni a ti dé báyìí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here